Mofiimu ni ege tabi fonran ti o kere julo ti o si ni ise ti o n se (tabi ihimo kikun) ninu ihunoro. Apeere eya moffimu ni oju, omo, owo, alaafia, eemi, egbon ati, ai, a, i, on. A ko le se atunge awon ege mofiimu oke wonyi mo ti a ba ge e, won yoo so itumo won nu.
Eya Mofiimu
A le pon mofiimu si orisii meji. Awon ni:
- Mofiimu Ipile (adaduro)
- Mofiimu afarahe
MOFIIMU IPILE TABI ADADURO: eyi je ege ti o le da duro lai i ni afikun fonran (afomo) miiran pelu re.
Mofiimu ipile maa n da itumo ni
A ko le fo mofiimu ipile si wewe mo. Mofiimu ipile le je:
- ORO – ORUKO: oro oruko bayii kii gba afomo mora, bee ni a kole pinwon si meji tabi ki a seda won. Apeere: Adebisi, Igbokoda, Adaye, Omi, Ile, Ori abbl.
- ORO – AROPO AFARAJORUKO: awa, eyin, awon, emi, iwo.
- ORO – ISE: lo, gbe, wa, de abbl
- ORO – APEJUWE: pupa, dudu, funfun
- ORO APONLE: banku, roboto
A le lo mofiimu afarahen moa won isori (ii – iv) oke lati seda ororuko titun. Bi apeere
ti + eyin ==== teyin
Awon oro – oruko kan wa ti a le se apehinpe won seda oruko tuntun. Bi apeere
Irun + agbon ====== irungbon
Mofiimu Afarahe
Mofiimu afarahe tabi afomo je awon iro (leta) inu ede ti ko le duro bi oro kan lai je pe a kan mofiimu ipile mo won. A le pin mofiimu afarahe sei meji:
- Afomo afarahe ibere (iwaju) mofiimu ipile ni an fi afomo kun ni ibere lati seda oro-oruko miiran. Afomo ibere le je ……
- Eyo faweli airanmupe bii: a, e, ȩ, i, o, ǫ, u ki a wa fi kun mofiimu ‘ipile’. Apeere
I + fe
I + gbagbo
A + de
E + to
E + ko
O + sere
Ǫ + muti
- Akanpo iro onisilebu meji bii ai, on, oni, ati, sai, abbl. Apeere
ai + sun
on + te
oni + isu
ati + je
sai + gboran
- Afomo afarahe aarin. Afomo aarin maa n waye ni aarin oro-oruko mofiimu adaduro ti a se apetunpe re. wunren afomo aarin ni; de, ki, je, ku, ni, si, ri, abbl. Apeere
Oro Oruko Afomo aarin Oro Oruko Abajade
Ile ki ile
Iran de iran
Ije ku ije
Emi ri emi
Agba ni agba
Opo ni opo
Ebi si ebi