AKORI EKO: AROKO ONI-SORO-N-GBESI

Aroko ti a ko to da lori itakuroso laaarin eniyan meji tabi ju bee lo ni a n pen i aroko oni-soro-n-gbesi.

Abuda Aroko Onisoro-n-gbesi

  • O maa n ni akopa bii ere ori itage
  • Oro enu akopa kookan maa n han ni iwaju oruko won
  • Iso bee ko gbodo gun ju, ko si se regi
  • Oro erin ati awada kii gbeyin, a si gbodo year fun awada ako
  • Isesi won ni a maa n fi sinu ami akamo olofo ( ).

E je ki a ka aroko oni-soro-n-gbesi yii wo, bi apeere:

(Won sese gbe oga titun kan de si ile-iwe re, ko iforo-jomi-tooro oro to waye laarin akekoo meji lori oga titun yii sile).

OGA TITUN

(Ranti ati Yemisi wa ni Kilaasi S.S.2. Won pade ni ikorita meta ni eba ile ounje. Yemisi fe lo kawe, Ranti fe lo pon omi)

Ranti:               (o sunmo Yemisi) E ma si ku amojuba t’Oga titun

Yemisi:            Baa se ki ni naa nu un. N o kuku tii ri won soju

Ranti:               Ma je k’aye o gbo. Iya to wa si ipade apejopo akekooati oluko ni aaro ana

Yemisi:                        (o mo’ju tai) Se won ni mow a n’be ni? Mo pe de. Kilaasi ni mo gba lo taara

Ranti:               Eyin isa-n-sa. Oju yin re e. ipade ohun ma larinrin

Yemisi:                        Ki lo sele? Won fun yin lo’oyin la? Gbee si mi leti, joo

Ranti:               Oyin ko, ado ni. Won kan fi oga han wa ni. Oun alara si gba wan i iyanju pe ki a tepa mose.

Yemisi:                        Eyuun lo wa mu ipade dun? Osise ni wan i?

Ranti:               Ki lo fe ki iya-oniyaa so? Oro iyanju ni akekoo n fe. Abi lo fe ko so. O kuku ti se’pade pelu awon oluko ati awon pirifeeti.

Yemisi:            (O tewo pe e) Igba wow a ni ‘pade tiwa? Abi?

Ranti:               Ipade wo ni o fe ki Alaaja tun ba wa se?

Yemisi:            Wa na, se Musulumi ni?

Ranti:               Musulumi ponbele ma ni. O kirun ju awo lo. Oro po. Iya naa le soro lataaro dale!

Yemisi:            Awon akekoo Musulumi bo saye nu un. Logan ni yoo ko Mosalasi ti won ti ko pati lati bi odun merin.

Ranti:               O ma ni oun ko boroesin wa. O ni bi esi idanwo asejade wa yoo se gbe peeli soke sii ni o je oun logun.

Yemisi:            Too. Olorun a fun un se. Awon alale a tii leyin

Ranti:               Ti awon alale ti se wa je ninu oro ile iwe?

Yemisi:            Ki lo fe n so? Se bi, won ni ‘Isese lagba’?

Ranti:               Ooto ma kuku ni. Obatala a ba a f’ase sii

Yemisi:            Ase o

(won pinya)

ALAYE

Iwontunwonsi afo enikookan se regi. Ede won lo taara, bee ni awada ibe mo niwon. Akekoo

meji pere ni a lo. Ko dara ki akopa po repete.

 

ISE AMUTILEWA

  1. Ko abuda aroko oni-soro-n-gbesi marun-un ti o mo
  2. Ro o lokan ara re pe iwo (Femi) ati ore re (Bayo) lo woran are Boolu afesegba to waye laarin Super Eagles ati iko agbaboolu Argentina. Super Eagles feyin won bale ni amin ayo merin si ookan. Eyin mejeeji wa n foro jomi-tooro or obo wa si ile. Bi oro naa se lo re e:

 

See also

AKORI EKO: ATUNYEWO ISE ABINIBI

AKORI EKO: ATUNYEWO LORI SILEBU EDE YORUBA

AKORI EKO: AROKO AJEMO – ISIPAYA

AKORI EKO: MOFIIMU

AKORI EKO: ATUNYEWO AAYAN OGBUFO

Leave a Comment

Your email address will not be published. Required fields are marked *