AKOLE ISE: KIKA IWE APILEKO TI IJOBA YAN

AKOLE ISE:          Igbagbo Yoruba Nipa Orisirisi Oruko Ile Yoruba.

Igbagbo Yoruba ni pe “ile la n wo ki a to so omo loruko”. A kii dede fun omo ni oruko ni ile Yoruba, akiyesi iru ipo ti omo naa wa nigba ti a bi, ipo ti ebi wa tabi ojo ati asiko ti a bi omo naa ni yoo so iru oruko ti a o so iru omo bee ni ile Yoruba.

 

Isori Oruko nile Yoruba

Oruko abiso

Oruko amutorunwa

Oruko Oriki

Oruko abiku

Oruko inagije

Oruko idile.

 

Oruo Abiso: Eyi ni oruko ti a fun omo ni banu pelu iru ipo ti obi, ebi, idile, agbegbe tabi ilu wa. Ba kan, o n toka igba ati asiko ti  a bi omo naa. Apeere ati itunmo irufe oruko bee;

Otegbeye:          Omo ti a bi leyin ote ilu ti ote naa si ja si eye ninu ebi

Tokunbo:             Omo ti a bi si oke okun

Abi ona:               Omo ti a bi si ona

Babajide:             Omokunrin ti a bi ni asiko ti baba agba ku.

Fijabi:                   Omo ti a bi Iasiko ti ija wa ninu ebi tabi omo ti abi ja si.

 

Oruko Amutorunwa:  Eyi ni oruko ti a n fun awon omo ti o gba ona ara waye tabi ti won mu nkan ara waye lara eya ara won.  Apeere ati itumo oruko bee:

Taiwo:                  Omo ti o koko jade nigba ti abi ibeji

Kehinde:             Omo ti o tele Taiwo, oun ni Kehinde gba egbon.

Dada:                    Omo ti irun ori re ta koko nigba ti abi

Ige:                        Omo ti o mu ese waye

Ojo:                       Omo kunrin ti a bi ti o gbe ibi ko run

Aina:                     Omo binrin ti a bi ti o gbe ibi ko run

Olugbodi:            Omo ti a bi ti oni ika owo tabi ika ese mefa abbl.

 

Oruko Oriki:  eyi ni oruko iwuri ti awon Yoruba n fun omo tuntun lati fi ki ni tabi gboriyin fun eniyan.  Apeere.

 

Oruko Oriki Okunrin: Akanni, Ajani, Ajao, Adufe, Akande, Alade, Akanbi, Abefe, abbi.

 

Oruko Oriki Obinrin:  Asake, Ayoka, Awele, Anike, Ajike, Asabi, Amope abbi.

 

Oruko Abiku:  Eyi ni oruko ti a fun omo ti o je pe bi won se n bi lo n ku.  Iru awon omo bee le para odo iya won lee meta tabi ju bee lo ki won to le duro gbe ile aye.

 

Apeere irufe oruko bee ni,

Akisatan, Durojaye, Malomo, Kokumo, Kosoko, Matanmi, Aja, Omitanloju, Kasimowoo, Durosinmi, Bamijoko, Omolanbe,.

 

Oruko Inagije

Eyi ni oruko apeje tie bi ore fun eniyan kan tabi eyi ti enyan fun ara re lati buyi kun ni tabi eyi ti won fun enyan kan nitori iwa re.  Apeere.

Olowojebute, Owonifaari, Ekun, Olowomojuore, Dudumaadan, Epolanta, Eyinfunjowo, Eyinmenugun, Awelewa, Aponbepore, Ibadiaran abbl.

 

Oruko Idile: Orisi idile ni o wa ni ile Yoruba, opo idile ni o si ma fun awon omo won ni oruko ni idamu pelu ipo idile, orisa ati ise abinibi ti won n se.

 

Apeere:

Idile Oloye:                        Oyeniyi, Oyeyemi, Oyede, Oyewunmi

Idile Alade:                        Adekanmibi, Adegbite, Adesina

Idile Ola:                             Oladoye, Oladapo, Afolabi, Olayomi

Idile Olorisa:      Orisatole, Orisabunmi, Orisatade

Idile Ode:            Oderinde, Odelana, Odefunke

Idile Ogun:         Ogunbiyi, Ogunleke, Ogunmole

Idile Onifa:         Faleti, Falade, Awojobi, Awolowo

 

Eka Isa: Litireso

Akole IseKika iwe apileko Oloro geere ti ijoba yan.

 

Igbelewon:

  • Kin ni akoto?
  • Salaye awon iyato ti o wa ninu sipeli aye atijo ati ti ode-oni
  • Ko isori oruko ile Yoruba pelu apeere okookan won

Ise asetilewa: Gege bi omo ti o jade lati ile ire, ko oruko ti o jemo idile re yala nipa ise tabi awon ohun ti a mo mo idile re mewaa.

 

See also

AKOLE ISE: AKAYE OLORO GEERE

Akole ise: onka Yoruba (300-500)

Onka Yoruba (101 – 300)

LITIRESO ALOHUN TO JE MO AYEYE

Leave a Comment

Your email address will not be published. Required fields are marked *