Oge sise ni a n pe ni oso. Oso ara, oso ile. Ki a se itoju ara, aso, ile ni gbogbo e dale lori. Ki a se itoju irun: irun didi, irun gige, iwe wiwe, enu fifo, ara pipa/jija eekanna gige ati bee bee lo ni a n pe ni imototo. Apeere oge sise nile Yoruba ni aye atijo ni ara finfin, eyin pipa, tiroo lile, laali, irun didi, enu fifo, ara pipa/jija ati bee bee lo. Eni ti o n maa n se itoju ara re ni a n pe ni afinju nigba ti a n pe eni ti ki i se itoju ara re ni obun.
Ara finfin: Ara finfin je okan lara oge sise ile Yoruba.Oloola (awon to maa n ko ila fun eeyan ) ni o maa n se ara finfin fun eeyan. Won le ya orisiirisii batani si ara eniyan bi alangba, Ooya idirun tabi akekee. Gbogbo nnkan won yii ni won n lo lati bu kun ewa ara won.
Eyin Pipa: Eyin pipa ni asa ki a da iho tabi alafo si aarin eyin meji to wa laarin gbungbun enu. Awon Yoruba gba pe eni ti o ba ni eji maa n ni ewa. Awon oloola ni o maa n se eyi pelu.
Tiroo: Awon obinrin ni ni o maa n le tiroo ju. Won yoo maa fi igi iye ediye le si oju. O maa n wulo fun oju pipon ati eyikeyi arun oju. Awon iya olomo naa maa n lo o fun omode, ero won ni wi pe o maa n mu idoti kuro loju.
Laali: Awon obinrin maa n le laali si atelewo ati egbeegbe ese won mejeeji. Bi o ba gbe tan won yoo ko ewe laali yii kuro ni oju ibi ti won ti koo kuro yi maa n dudu lati bu kun ewa won. Iru eyi maa n wopo ni Igbomina/Ilorin ati eya Hausa.
IGBELEWON:
- Kin ni oge sise?
- Ko ona merin ti a n gba soge laye atijo.
IWE AKATILEWA:
1 Eko ede Yoruba titun (SSS) iwe kin-in-Eko ede ati asa Yoruba iwe kin-in-ni (JSS 1) oju iwe 90 – 93 lati owo egbe akomolede ati asa Yoruba.
2 Eko ede Yoruba titun iwe kin-in-ni (J S S1 ) oju iwe 153-158 lati owo Oyebamji Mustapha.
APAPO IGBELEWON
- Fa 8lz s7 8d7 =r= 8se n7n5 zr0k[ y87:
On7r5ur5 kzy34f8 ni 9 k5n il3 ay3. Ol9w9 zti tql7kz l[ s6z. {l-gb-n 0un 0m6g= l[ bi r1rc. Ibi 8gb7n ti n sunk5n z8l9r7 ni zjznzk5 ti n pariwo or7 t7t9bi. Cni in5 n run n jow5 cni or7 n f-. Il3 ay3 y87 nqz ni K-l3dow9 ti bi [m[ m1j[ t7 Oy7b9y7 fi w[n dqj[, t7 8yq ol9w9 y[y[ wq di zgzn =sqn-an-gan.
- Salaye lori oge sise abinibi ile Yoruba.
ATUNYEWO EKO
- Salaye lori aseyinwaye.
- Salaye lori asa eewo nile Yoruba.
- Salaye lori eto abinibi nie Yoruba.
ISE ASETILEWA
- _____ ni opomulero fun gbolohun (a) oro-oruko (b) oro-ise (d) eyan
- E rowa ro ire je apeere oro-ise _____ (a) asoluwadabo (b) alapepada (d) agbabo
- Sola da obe nu. Oro_ise iru gbolohun yi ni (a) da (b) obe (d) danu.
- Awon wo lo maa n lo laali ju? (a) obinrin (b) okunrin (d) omode (e) arugbo
- Idi ti won fi maa n korin nibi ikomojade ati igbeyawo ni _________ (a) ounje jije (b) nitori ilu lilu ti o wa nibe (d) nitori a ki i saba korin lojoojumo (e) inu didun
APA KEJI
- Salaye iyato meta laarin oro aropo oruko ati oro aropo aafarajoruko.
- Salaye iyato marun-un laarin oro oruko ati oro aropo oruko.
- Ko orisii ila marun-un ti awon Yoruba n ko.
See also
ETO ISELU ABINIBI ATI ODE ONI