Gbolohun ni afo ti o kun to si ni ise to n se nibikibi ti won ba ti je jade.
Gbolohun ni iso ti o ni itumo kikun.
Orisi eya gbolohun ti o wa ninu ede yoruba
- Gbolohun abode
- Gbolohun ase
- Gbolohun ibeere
- Gbolohun alaye
- Gbolohun iba/kari
- Gbolohun ayisodi
- Gbolohu akiyesi alatenumo
- Gbolohun asoduruko
- Gbolohun alakanpo abbl.
- Gbolohun Abode (Simple Sentence):- Eyo oro ise kan ni gbolohun yii maa n ni bee ni kii gun.
Mo ra isu
Ayomide rerin-in
- Gbolohun ase:- Gbolohun yii ni a n lo lati fi pase fun eni ti an ba soro. Apeere;
E dide jokoo
Wa ri mi
Da ke je
- Gbolohun ibeere:- Eyi ni lilo awon wunren ibeere lati fi se ibeere. Atoka bi, tani, ki ni, ba wo, me loo, nje, sebi abbl. Ni a n lo lati fi se ibeere. Apeere;
Se Olu wa?
Ta ni o jale?
- Gbolohun alaye:- Eyi ni a fi n se iroyin bi isele tabi nnkan se ri fun elomiran lati gbo. Apeere
Ise ojo oni ti pari
Mo lo si ilu oba losu to koja
- Gbolohun alakanpo :- Gbolohun yii ni a maa n fi oro asopo so awon gbolohun miran po di eyo gbolohun kan. Oro asopo bii, ati, sugbon, omo, tabi, abbl.
ni a n lo lati fi kan gbolohun meji po. Apeere ;
kunle ati olu lo si oja
abike jeun sugbon ko yo abbl.
Igbelewon :-
- Fun gbolohun ni oriki
- Irufe gbolohun wo ni wonyi ?
- Se o daa bee?
- Ade ra eja
- Pe e wa dun mo wa ninu
- A ko tii lo
- Bola lo sugbon ko baa
Ise Asetilewa:- yoruba Akayege iwe amusese fun ile eko sekondiri kekere iwe keji lati owo L. Orimogunje, K. Adebayo, F. Okiki(2012) Oju Iwe kejila Eko kefa
Asa:- Asa Iwa Omoluabi
Iwa lewa, bee si ni iwa rere ni eso eniyan. Iwa eniyan a maa fi eniyan han, iru eni ti eniyan je nitori « eefin niwa ».
Ojuse Omoluabi Si Obi
- Kiki awon obi ni gbogbo akoko
- Jije ise fun obi ni gbogbo igba
- Mimo riri ati iyi obi
- Gbigba ati titele imoran rere lati enu awon obi
- Bibu ola fun an obi ni gbogbo igba
Ojuse Omoluabi Si Ijoba/Awujo
- Sise imototowo ayika
- Pipa ofin ati ilana agbegbe tabi orile ede mo
- Jije olododo ninu ise eni
- Sisan owo ori fun ijoba lati pese ohun amayederun
- Lilowo ninu ise ajumose lawujo
Igbelewon:-
- Ko ojuse omoluabi si obi marun-un
- Ojuse omoluabi ko kere ni awujo ko ojuse omoluabi merin si ijoba.
Ise Asetilewa
- Okan lara awon iwa omoluabi ni __________ (a) oro siso (b) ounje jije (d) i se sise
- Ise ati iwa omoluabi bere lati ______ (a) inu ile (b) ile iwe (d) ile iwosan
- Ki ni omoluabi gbodo se fun awon obi ________ (a) bu obi (b) na obi (d) bowo fun obi
- Bi omoluabi ba ri agblagba ti o ru eru, o gbodo __________ iru eni bee lowo (a) je (b) ran (d) bu
- Imototo lo le ________ aarun gbogbo (a) bori (b) gbe (d) segun
LITRESO- KIKA IWE TI IJOBO YAN
See also
Ede:- Akaye onisoro-n-gbesi
Ede:- ilana Kika akaye onisorongbesi
Ede:- Akaye oloro geere
Ede:- Akaye Oloro Geere wuuru
Ede:- Aroko Asotan/Oniroyin (Narrative Essay)