Gbolohun ni akojopo oro ti o ni oro-ise ati ise ti o n je nibikibi ti o ba ti jeyo.
Eya gbolohun pin si ona meji
- Gbolohun Abode/eleyo oro-ise
- Gbolohun onibo/olo po oro-ise
Gbolohun Abode/Ele yo oro-ise
Gbolohun Abode je gbolohun ti kii gun
Gbolohun Abode kii ni ju oro-ise eyokan lo. Apeere,
- Bata re ja
- Adufe sun
- Oluko ko ise
- Dayo fe iyawo
Ihun gbolohun abode/eleyo oro-ise
- Gbolohun eleyo oro-ise le je oro-ise ni kan: – Apeere; lo, jokoo, wole, jade, gbo, fe, abbl.
- Gbolohun eleyo oro-ise le je oluwa oro-ise ati oro-aponle. Apeere
- Ile ga gogoro
Oluwa oro-ise oro-aponle
- Jolade sun fonfon
Oluwa oro-ise oro aponle
(D) Gbolohun eleyo oro-ise le je oluwa.
- Oro-ise kan ati abo. Apeere
- Ige je iyan
Oluwa oro-ise abo
- Asake pon omo
Oluwa oro-ise abo
(E) Gbolohun eleyo oro-ise le je oluwa, oro-ise kan, abo ati apola atokun. Apeere
- Aina je eba ni ana
Oluwa oro-ise abo apola atokun
- Ojo gbe owo si ori
Oluwa oro-ise abo apola atokun
(E) Gbolohun eleyo oro-ise le je Oluwa, oro-ise kan ati apola atokun. Apeere,
- Folakemi lo si odo
Oluwa oro-ise apola atokun
- Idowu lo si oja
Oluwa oro-ise apole atokun
(i) folakemi lo si odo
Oluwa oro apole atokun
(ii) Idowu lo si oja
Oluwa oro ise apole atokun
Gbolohun onibo/olopo oro –ise
Eyi ni gbolohun ti a fi gbolohun miran bo inu re. apeere re;
(i) Awon ole yoo sa bi awon ode ba fon fere
Alaye:- (a) Awon ole yoo sa
(b) Bi awon ode ba fon fere.
Gbolohun oke yii je gbolohun keji. A le gbe won fun ra won bay ii ti won ko si ni so itumo gbolohun naa nu;
=) Ti awon ode ba fon fere awon ole yo sa – gbolohun onibo a saponle
(ii) Oko ti Ade ra dara
(a) Oko dara
(b) Ade ra oko
Gbolohun meji ni a gbe wonu ara won – gbolohun onibo asapejuwe. (descriptive)
(iii) O dara pe o rise si ile-epo – pe o rise si ile-epo o dara – gbolohun onibo asodoruko (personification).
Igbelewon:-
- Kin ni gbolohun?
- Eye meloo ni gbolohun pin si?
- Saleye gbolohun abode ati onibo pelu apeere meji meji.
Ise Asetilewa:-
Irufe gbolohun wo niyi :
- Bola ra aso
- Awon akekoo yoo se aseyori ti awon Oluko ba ko won
- Tomi pon omi
- Baba agba ko ni ku bi awon Dokita ba se ayewo to to fun un
- Yomi fe iyawo
ASA – OGE SISE NI ILE YORUBA (FASHION)
Oge sise je asa imototo ati sise ara losoo.
Awon ona ti a n gbe se oge ni ile Yoruba laye atijo.
- Iwe wiwe:- Eyi maa n mu ara eniyan mo tonitoni bee ni ou san bi kuruna, ara wiwo yoo jinna si eni to ba n we dee de.
- Aso wiwo:- Awon Yoruba ni igbagbo pe aso lo n bo asiri ara, idi niyi ti awon Yoruba fi n da oniruwu aso fun igba ayeye lorisiris. Aso bii, Dansiki, Kenbe, Agbada, Buba ati soro fun awon okunrun, iro ati buba, gele, iboru ati ipele fun awon obinrin
- Itoju irun ori:- Eyi se Pataki nitori na ni Yoruba fi n pa owe pe “Irun kikun ni ipilese were”. Ona ti awon obinrin fi n toju irun won ni irun didi ni aye atijo. Orisirisi irun didi bii, suku, patewo, ipako elede, panumo, kolese, koju-soko, koroba abbl ni o gbajumo laarin awon obinrin. Awon ti o n di irun ta ni onidiri”.
Awon okunrin a maa fa irun ori, ge irun ori tabi dida osu si ori bii oni sango.
- Tiroo lile:- Asa obinrin ni tiroo lile, ko wopo laarin okunrin. Ti roo maa n mu ki oju tutu ki o si dun-un wo be ni o dara fun awon ti eyinju won maa n pon lati le je ki idoti oju won ba ipin oju jade.
- Laali lile:- Aajo ewa ni laali lile. Aarin Hausa ati tapa ni o wopo ju si. Awo elesin musulim ni o mu loo inu asa Yoruba.
- Ila oju kiko:- Ila kiko je asa Yoruba lati da eru mo si ojulowo omo ni aye atijo. Ila kiko wopo laarin awo oyo, ibadan, ogbomoso, ondo, osogbo, abbl. Apeere ila kiko ni, pele, abaja, olowu, gonbo, bamu, keke, ture, abbl.
OGE SISE LODE-ONI
- Aso wiwo:- Oniruru aso igbalode ni okunrin ati obinrin n wo lode-oni. Aso obinrin-solate, kabe, bonfo. Tabi mafogota ati bilaosi.
Aso Okunrin:- Kootu, seeti, tai ati sokoto tinrin
- Lilo ohun eso bii bata, bagi, biidi igbalode, goolu ati selifa, oruka owo ati ese
- Itoju oju, enu ati ete bii, leedi ati atike alawo oniruuru, itote ni oniruuru awo.
- Itoju ara:- Yiya tatuu si ara .
- Itoju irun ori:- Awon obinrin ama fo irun ori tabi ki won jo o ni ina, lilo wiigi, fifi adamodi irun kun irun ki owo re le gun lo gbode kan loni.
Awon Okunrin a maa ge sitai ori bii, bob merley koko, weefu, all back abbl.
Aleebu oge-sise lode-oni
- Olaju iwe ati asa ti mu ki oge sise yato ni ile Yoruba
- Opo aso ode-ori kii bo asiri ara mo.
PATAKI OGE-SISE
- O n je ki ara eniyan mo toni toni
- O n le aisan jinna si eniyan
- Ko kii je ki ara wo ni
- O n bo asiri ara
- Tiroo lile maa nti idoti oju jade
- O n bu ewa kun ni
Igbelewon:–
- Fun oge sise ni oriki
- Ko ona marun-un ti a n gbe se oge laye atijo
- Salaye aleebu ogesisi lode-oni ni soki
ISE ASETILEWA:-
Yoruba akayege iwe Amusese fun ile eko sekondiri kekere iwe kin-in-ni lati owo o L. Orimogunje, K. Adebayo, F. Okiki. Oju iwe kejilelogun Eko kejidinlogun
LITIRESO:- Orin Ibile To Jemo Asa Igbeyawo, Pipa Ogo Obinrin Mo Ise Agbe Ise Ode.
Orin to je mo asa igbeyawo
- Tun mi gbe
Oko mi tun mi yan
Iyawo dun lo sin-gin
Irin eyi wu wa o
Iyawo dun losin-gin o
Tun mi gbe
- Baba mo mi lo
Fadura sin mi o
Iya mo mi lo
Fadura sin mi o
Kin maa kesu
Kin maa kagbako nile oko
Kin maa kesu
Kin maa kagbako nile oko
Iya mo mi lo
Fadura sin mi o.
Orin ibile to je mo ise Agbe:-
Ise agbe nise ile wa
Eni ko sise, a maa jale
Iwe kiko lai si oko ati ada
Ko I pe o!
Ko I pe o!
Orin ibile to je mo pipa ogo obinrin mo:-
Ibaale ibaale o!
Ibaale logo’binrin
Ibaale o!
Olomoge pa’ra re mo
Pa’ra re mo o
Ibaale logo obinrin
Ibaale o!
Iwulo/Pataki orin
- O wa fun idoraya
- O n mu inu eni dun
- O wa fun iwuri
Igbelewon:- Ko orin ibile meji meji fun awon Asa ati ise ibile wonyi:-
- Igbeyawo
- Pipa ogo obinrin mo
- Ise agbe
Ise Asetilewa:- Yoruba akayege iwe Amusese fun ile eko sekondiri kekere iwe kin-in-ni lati owo o L. Orimogunje, K. Adebayo, F. Okiki. Oju iwe kejidinlogun Eko kerinla
See also:
Ede:- Atunyewo orisirisi gbolohun ede Yoruba
Ede:- Akaye onisoro-n-gbesi
Ede:- ilana Kika akaye onisorongbesi
Ede:- Akaye oloro geere
Ede:- Akaye Oloro Geere wuuru