Litrreso alohun ni litireso ti a fi ohun enu gbe jade ti a jogun lati odo awon babanla wa.
Apeere litireso alohun ajemayeye ni
i Ekun Iyawo
ii rara
ii Bolojo
iv Apepe
v Dadakuada abbl
Ekun iyawo gege bi litireso alohun ayeye
Ekun Iyawo je ewi ti omo binrin ti n lo si ile oko maa n sun lojo igbe yawo.
Koko inu ewi ekun iyawo
- O n je ki a mo riri itoju ti awon obi re se lori re lati igba ewe.
- O wa fun idagbere fun ebi ati ara
- O wa fun omobinrin lati bere imoran lodo obi
- O wa fun eko fun awon wundia to ku lati pa ara won mo dojo igbeyawo
Agbegbe ti ekun iyawo ti n waye,
i Ilu iseyin
ii Ilu Ikirun
iii Ilu Osogbo
iv Ilu Oyo Alaafin
v Ilu Ogbomoso abbl
Rara gege bi litireso alohun Ajemayeye
- Rara je litireso alohun atigbadegba lawujo Yoruba.
- Awon obinrin ile ti won mo itupale oriki orisun oko ni won maa nfi rara sisu pon oko won le.
- Akoko ayeye bii ifinijoye igbeyawo, isomoloruko, isile abbl ni awon asurara maa n sun rara ju lati fi ki awon eniyan ja-n-kan lawujo.
- Asun rara le je Okunrin tabi obinrin
Agbegbe ti awon asurara wopo ju si,
I Ede v Oyo Alaafin
ii Ikirun vi Iseyin
iii Ogbomoso vii Ibadan abbl
iv Osogbo
Bolojo gege bi litireso alohun ajemayeye
- Awon omokunrin yewa ni o n sabe maa n ko bolojo lati fi se aponle, tu asiri ,se efe, soro nipa oro ilu, oro aje abbl.
- Won maa nko bolojo ni ibi ayeye bii, igbeyawo, isomoloruko, oye jije, isile abbl.
Igbelewon:
- Kin ni akoto?
- Ko oro atiji mewaa ki o si ko akoto irufe awon oro bee
- Fun litireso alohun ni oriki
- Ko litireso alohun ajemayeye marun un ki o si salaye
Ise asetilewa: ko apeere ewi ekun iyawo kan lati fi han pe obinrin ti o n lo ile oko ni o maa n sun ekun iyawo lati fi moriri awon obi re.
See also
Ami Ohun lori oro onisilebu meji