AKOLE ISE – SISE ATUNYEWO FONOLOJI EDE YORUBA

Fonoloji ni eko nipa eto iro.

A le saleye eko nipa eto iro labe awon ori oro wonyi ninu ede Yoruba

 

Atunyewo faweli ati konsonanti

faweli ni iro ti a pe nigba ti ko si idiwo fun eemi.

 

Iro faweli pin si ona meji,

Scholarships 350 x 250a
  1. Iro faweli airanmupe (7) meje

Aa     Ee     Ee     Ii     Oo     Oo     Uu

  1. Iro faweli aranmupe (5) marun-un

an       en      in       on     un

 

Bi a se n ko faweli ni ilana fonetiki niyi

A      [ a]

e      [e]

e       [e]

i        [i]

o       [o]

o       [ o ]

u       [u]

an      [  an]

en      [Ệ]

in       [Ῐ]

on      [ on]

un     [u]

Konsonanti ni iro ti a gbe jade nigba ti idiwo wa fun eemi.

Apapo konsonanti ede Yoruba je meji-dinlogun (18)

Bi a se n ko konsonanti ni ilana fonetiki.

b [b]

d [d]

f [f]

g [g]

gb [gb]

h [h]

j [j]

k [k]

L [L]

M [m]

n [n]

p [kp]

r [r]

s [s]

ṣ [  ]

t [t]

w [w]

y [j]

ATUNYEWO SILEBU

Silebu ni ege oro ti o kere julo ti eemi le gbe jade lee kan so so lai si idiwo.

Iye ami ohun ti o jeyo ninu oro kan ni iye silebu iru oro bee.

 

IHUN SILEBU

  • Faweli nikan (F)
  • Apapo konsonanti at faweli (KF)
  • Konsonanti aranmupe asesilebu (N)

 

Apeere silebu faweli nikan  (F)

  • Mo sun un je
  • Oluko ran an leti ounje
  • Mo ri i
  • Mo ra a

 

Akiyesi: Gbogbo faweli airanmupe ati faweli aranmupe le duro gege bi silebu kan ninu oro.

Apeere apapo konsonanti ati faweli (KF)

  • Gb + o
  • R + in
  • W + on
  • T + a
  • J + e

Apeere konsonanti konsonanti aranmupe asesilebu (n)

  • Tade n je isu
  • Mo n lo
  • Ba-n-gba-de
  • o-ge-de-n-gbe

Akiyesi: Konsonanti aranmupe asesilebu le duro gege bii silebu kan.

 

Eka ise: Asa

Akole Ise: ATUNYEWO AWON ASA NINU ISE OLODUN KIN-IN – NI.

Asa ni iwa ajumolo awon eniyan ati isesi won. Yoruba ka asa si lopolopo, orisirisi asa si ni awon Yoruba le mu yangan lawujo. Lara awon asa naa niyi

  1. Asa iranra-eni-lowo
  2. Asa ikini
  • Asa ogun jije abbl.

 

ASA IKINI

Asa ikini je okan lara iwa omoluabi ti a gbodo ba lowo omo ti a bi, ti a ko ti o si gba eko rere.

Yoruba bo won ni “ka ri ni lokeere, ka sayesi, o yoni, o ju ounje lo” ni ile Yoruba omokunrin maa n do bale gbalaja ti awon omobinrin yo si lo lori ikunle ti won ba n ki obi tabi awon ti o ju won lo.

Omo ti o ba ka asa ikini si ti o si n bowo fun agba, Yoruba ka iru omo bee si omo gidi, to gbon ti o si ni eko ile.

 

ASA OGUN JIJE.

Ti eru kan ba ku ni ile Yoruba, gbogbo dukia tabi eni ti o ba fi sile ni a n pe ni ogun.

Eto wa lori bi a se n pin ogun ni ile Yoruba. leyin ti won ba ti sofo eni ti o ku tan ni won maa n pin ogun re ki dukia re maa ba da ija sile.

Eni ti o ba dagbe ju ninu agboole kan ni o maa n seto ogun pinpin ni ile Yoruba, awon agba yii yoo se iwadii bii oloogbe se se ilana pinpin ogun re sile ko to jade laye, ti eyi ba wa, won yoo lo o,  sugbon ti ko ba si , awon agba ile yoo lo laakaya won lati se iwadii lori gbogbo ohun ti oloogbe fi saye won yoo si pin bi o ti to laaarin awon omo, iyawo ati aburo oloogbe.

Lara awon ohun ti a le pin gege bii ogun ni ile, ile, aso, oko, iyawo, omo oku to kere, oso ara, gbese abbl.

 

ASA IRANRA-ENI LOWO

Asa iranra-eni lowo je okan lara ona ti Yoruba n gba lati ran ara won lowo nibi ise won gbogbo.

Orisi ona ti Yoruba n gba ran ara won lowo laaye atijo niyi,

  1. Esusu: Iye owo ti eniyan ba da ni yoo gba
  2. Ajo: Eniyan le gba ju iye ti o ba da lo
  • Owe: Omokunrin ti o ni iyawo ni o maa n be awon ore re lowe
  1. Aaro: Sisise ni oko awon ti o sun mora titi yoo fi kari
  2. Aroko doko: Eyi ni sisise ni oko eni-kookan titi yoo fi kari sugbon kii se oko awon ti o sun mora nikan.

Lode-oni: Egbe alafowosowopo je ona ti a n gba ran ara eni lowo.

Egbe yii n bo asiri nipa yiya ni lowo , o si fi aaye sile lati daa pada ni diedie.

 

EKA ISE: LITIRESO

AKOLE ISE: ATUNYEWO AWON EWI ALOHUN YORUBA.

Litireso ni akojopo ijinle oro ni ede kan tabi omiiran.

Litireso alohun je apa kan ninu isori litireso. Eyi ni ewi ti a jogun lati enu awon babanla wa.

Lara awon ewi alohun Yoruba ni,

  • Ofo
  • Oriki
  • Ese-ifa
  • Ayajo
  • Ogede abbl.

Ewi je akojopo oro ijinle ti o kun fun ogbon, imo ati oye.

Ese-ifa: O je amu fun ogbon, imo ati oye awon Yoruba. Orunmila ni orisa awon onifa.

Ofo: Ofo je awon oro ti a n so jade ti a fi n segba leyin oogun tabi ti a n pe lati mu ero okan wa se.

Ayajo: inu ese-ifa ni a ti mu ayajo jade. Oro enu lasan ni ko nilo oogun bii ti ofo.

Ogede: Ohun enu ti o lagbara ju ohun enu lo ni ogede. Eni ti o ba fe pe ogede gbodo bii ero ki o to le pe ogede bee ni yoo ni ohun ti yoo to le bi o be ti pee tan.

Oriki: Yoruba n lo oriki fun iwin a ni oriki oruko, oriki orike, oriki boro kinni, oriki idile abbl.

 

Igbelewon:

  • Fun fonoloji loriki
  • Sapejuwe iro faweeli ati iro konsonanti
  • Kin ni silebu?
  • Salaye ihun silebu ede Yoruba
  • Fun asa loriki
  • Daruko awon asa ile Yoruba
  • Salaye awon asa naa ni kukuru

Ise asetilewa: salaye asa iranra-eni lowo ode-oni lekun-un rere

 

See also

ATUNYEWO AMI OHUN ATI SILEBU EDE YORUBA

AKORI EKO: ERE IDARAYA

AKORI EKO: ATUNYEWO AWON EYA GBOLOHUN

AKORI EKO: EWI AKOMOLEDE

AKORI EKO: APOLA INU EDE YORUBA

Scholarship 1
Acadlly

You cannot copy content of this page

error: Content is protected !!