Apola je okan ninu awon abala ihun gbolohun ede Yoruba. Gbolohun le je eyo oro kan tabi akojopo oro ti oni itumo. Ihun gbolohun ede Yoruba dabi igba ti a bah un eni, a ni lati to awon oro wonyii jo lona ti yoo fi le e mu itumo ti o gbamuse lowo. A tun le fi we awon ohun elo ikole ti o toju lorisirisii lona ti yoo fi gbe ile ti o dara, ti o si lewa jade.
Lara awon isori oro ti a to jo lati hun gbolohun ede Yoruba ni:
- Oro Oruko
- Oro Aropo Oruko
- Oro Apejuwe
- Oro Ise
- APOLA ORO ORUKO (NOUN PHRASE): Eyi le je oro kan tani akojopo oro ti a maa n lo gege bi oluwa ati abo ninu gbolohun yala pelu eyan tabi laisi eyan. Ihun apola oruko le je:
- Oro – Oruko kan soso pere: Ojo rǫ
- Oro – Aropo oruko: Mo sun
- Oro aropo afarajoruko: Eyin ni mo ri
- Apapo oro oruko pelu eyan:
Okunrin yen ni o mu
Ewure merin ni won pa bo ifa
Bola aburo Kemi ti wolu de
Ounje die ni ki o se
ȩ. Apapo oro – oruko ati awe gbolohun: Oro ti Kemi so dun won.
- APOLA ISE (VERB PHRASE): Apola maa n je eyo oro tabi akopo awon eyo oro ti o le se ise oluwa ninu awe gbolohun ati odidi gbolohun. O le je oro-ise ponbele, oro ise agbabo, asaaju oro ise ati enyan. Oun ni o n sise opomulero ninu gbolohun ede Yoruba. Bi Apeere:
Jokoo, sare, jade, dide, ati bee bee lo. Apeere:
Bisi ra iyan
Komolafe je efo
Ayo sese de Ijanikin
Gbadebo gbin ododo
- APOLA APONLE: Apola aponle ni awon oro ti o n se ise epon tabi eyan fun oro-ise ninu gblohun ede Yoruba. Apola aponle maa n fi itumo ti o kun fun oro-ise inu apola ise ni. Apola aponle ti maa n jeyo. Fun apeere:
O n tan yerieyeri
O n rin kemokemo
Aso funfun balau
O tutu niginnigin
Ise Asetilewa
Tooka si awon apola ti a fa ila si nidii ninu awon gbolohun isale yii:
- Ade jeun o si yo
- O mu oti lile
- Sare lo jeun
- Dide wa
- Ayinde rin jelenke
- Mo ra eran ogunfe
- Bisade rin pelepele
- Emi ni won pe
See also