AKORI EKO: ATUNYENWO LETA AIGBEFE (INFORMAL LETTER)

IGBESE LETA AIGBEFE

  1. Adiresi: Adiresi akoleta (The writer’s address)

Adiresi agbaleta (Receiver’s address)

  1. Deeti (the day’s date)

iii. Ikini ibeere (salutation)

  1. Akole leta (the tittle / heading)
  2. Koko leta (main content)
  3. Ikadii / ipari leta (conclusion)

 

Leta aigbagbefe / aigbefe (Formal letter)

Eyi ni leta ti a maa n ko si awon eniyan ti won wa ni ipo kan ni ibi ise adani tabi si ajo ilu. Leta bayii kii se enikan pato, eni ti o je oga ni akoko naa ni yoo kaa. Idi niyi ti a kii fi ko oruko eniyan Kankan sii.

Ninu leta aigbagbefe, ko si aaye fun iroyin tabi efe rara. Apeere iru leta yii ni a n ko si Ajele, Olofuu iwe iroyin, enwa ile – ise, oba, Alaga igbimo, Alaga ijoba ibile, oga ile – iwe ati akowe agba ibi ise ijoba apapo bii: oga agba ajo idanwo WAEC, NECO ati JAMB.

 

Igbese Leta aigbagbefe

  1. Adiresi: Adiresi meji nil eta aigbafe maa n ni
  2. Adiresi akoleta: eyi yoo wa ni owo otun oke iwe, deeti ojo ti a koi we yoo tele ni isale.
  3. Adiresi agbaleta: Eyi yoo wan i owo osi ni ila ti o tele deeti. Apeere:

Federal Government College,

Ilorin,

Kwara State.

2nd February, 2015.

Olotuu,

Iwe Iroyin Alaroye

34, Agbabiaka Street,

Lagos.

 

  1. Ikini Ibeere: Apa osi ni ila ta tele adiresi agbaleta ni akoleta yoo ko ikini akoko si leta n la ni o gbodo fi bere yoo si fi ami koma kadii re. apeere:

 

Olotuu,

Oga ile – iwe,

Akowe agba, abbl

  1. Akole leta aigbefe: Ila ti o tele ila ikini ni akoleta yoo ko akole leta re si ni aarin iwe yoo si fara sidii re ti o ba ti leta kekere ko o tabi ki o ko o nil eta nla lai fala si nidii. Apeere:

Ayeye Ojo Omiran Orile – Ede Naijiria.

  1. Ara leta: Aaye ko si fun iforo jewoo tabi awada ninu leta yii, ohun ti a ba fe so ni pato ni a gbodo gbe kale. Ti o ba si je esi iwe ti akoleta ko gba tele tabi ko ni a gbodo fihan.
  2. Ikadii/ipari: owo otun ni isale iwe ni akoleta yoo ko igunle leta re si, oruko meji (iyen ni oruko akoleta ati obi re) ni o gbodo ko pelu ami idanuduro ni ipari. Apeere:

Emi ni,

Biodun Agbabiaka.

(signature)

 

Ise Asetilewa

Ko leta si oluko agba ni ile – iwe re lati gba aaye fun ose kan nitori ailera re.

AWON ORISA ILE YORUBA ATI AWON EEWO WON

Eniyan ni awon orisa wonyii ni igba aye won (ifa, ogun, esu, sango, oya, osun abbl). Sugbon nitori akitiyan ati ise akoni won nigba ti won wa laye ni awon Yoruba se so won di orisa akunlebo. Paapaa julo, iru iku ti won ku ati ise won leyin iku won so won di eniyan oto laarin awon omo adari ti n irun.

  1. Ifa tabi Orunmila: Orunmila ni awon Yoruba pe ni Agbonmiregun, ayanmo tabi kadara eniyan ko seyin re, ko si ohunkohun ti eniyan le se laye ti ko ni mo nipa re. orisa yii je okan gboogi ninu awon ibe ti awon Yoruba ka si lopolopo, ifa dide (pelu ikin tabi opole) ni o maa n so ayanmo tabi ese – n – taye omo. Litireso atenudenu ti a maa n lo ti a ba n da ifa tabi se odun ifa ni a n pe ni iyere ifa, amaa n sun uyere ifa lati fi yin tabi ki ifa ni.

Ounje Ifa niwonyii:

  • Adie
  • Ewure
  • Eyele
  • Igbin
  • Eja
  • Epo pupa abbl.

Eewo Ifa

Awon olusin re ko gbogbo je iu titun saaju odun ijesu.

  1. Ogun:Agbe ni ogun nigba aye re, o si je akikanju nigba ti o wa laye. Ni aye ode – oni gbogbo awon ohun elo tabi irinse ti o ba je mo irin ni won maa n boo gun. Ijala ni ewi ti ab maa ri sun nibi odun ogun tabi ni ibi isipa ode.

Ounje Ogun niwonyii:

  • Aja
  • Iyan
  • Emu
  • Esun isu abbl

Eewo Ogun

Gbigbe ofifo agbe tabi akeregbe emu duro ni ojubo re.

  1. Sango: Oba ni Sango je ni igba aye re ni ode aye, o si je alagbara pupo ti o fi je pe ko si ogun ti oba Sango ko le koju nigba aye re, agbara re po to bee ti ina fi maa n yo lenu re nigba ti a ba n binu, gbogbo awon eniyan si maa n beru re. Iyawo meta ni Sango ni, awon no Osun, Oba ati Oya si jee aya re.

Ilu dite mo Sango nitori asilo agbara re, o fi ilu sile, Oya nikan lo si tele. Oya wole ni IRA o si di odo ti a mo si odo Oya. Sango pokun so nidii igi AYAN ni koso.

Awon elegun Sango maa n di irun ori won bii ti obinrin, aworo Sango ni a n pen i Baba Mogba.

Ounje Sango niwonyii:

  • Orogbo
  • Agbo funfun abbl

 

  1. ESU: Ilu ile – ife ni esu n gbe nigba aye re, o je oburewa, eniyan ESU fi igba kan koi se, ifa dida (awo) ni idi orunmila. O je eni to gbonu – gboya, ko si eni ti ko le ko loju, gbogbo ebo ti ESU bag be lo maa n fi (da). Orunmila maa n ran –an lo si odo Eledumare ni orun, idi niyi ti won fi n pe e ni “Agbayegborun”.

ESU maa n gba ija onija kann; a sit un maa n da ija sile laarin eniyan meji nigba aye re. igboju, akikanju ati ebo ti o n gbe to si n da, ni o je ki awon eniyan so di orisa leyin iku re.

Ounje Esu ni wonyii:

Gbogbo nkan tie nu n je ni ounje ESU

Eewo Esu

Tita adin si oju re

 

OWE ILE YORUBA

Owe ni akojopo oro ti o kun fun ogbon, imo yinle ati iriri awon agba. Owe yii ni awon agba maa n pa lati fi yanju oro to ba ta koko. Ni ile Yoruba, omode kii pa owe niwaju agbalagba lai ma toro iyonda lowo won, omode naa yoo so pe “ tooto o se bi owe”, awon agba ti o wan i ijokoo yoo si dahun pe “wa a ri omiran pa”.

Ona ti owe gba waye

  1. Akiyesi sise: Awo agba maa n sakiyesi awon isele ti o n sele ni ayika won lati seda owe. Bi apeere: Bi a ba gba ile, gba ita, aatan la n da a si.

 

  1. Esin: Opolopo awon owe ti awon baba n la wa maa n pa ni won waye nipase esin ibile won. Apeere: Aigbofa la n woke, ifa kan ko sin i para.

 

  1. Asa: inu okan – o – jokan asa Yoruba ni awon agba ti seda opolopo awon owe. Bi apeere: Ile la n wo, ki a to so omo loruko.

 

ISORI OWE

Ona marun – un ni isori owe pin si, awon nii:

  1. Owe fun imoran
  2. Owe fun alaye
  • Owe fun ibawi
  1. Owe fun ikilo
  2. Owo fun isiri
  3. OWE FUN IMORAN: ti oro ba doju ru, awon agba n a maa n to lo fun imoran to ba ye. Ni opolopo igba, owe ni won maa n pa lati to eniyan sona. Bi apeere:
  4. Ile ti ko toju eni su, okunkun re maa n soro o rin.
  5. Alagemo ti bimo re tan, aimojo ku sowo omo alagemo

d.Igi ganganran ma gun ni loju, okeere lati n wo o

  1. Oju mewaa ko ju oju eni
  2. Falana gbo tire, tara eni la n gbo

 

  1. OWE FUN ALAYE: Awon owe kan wa ti awon agba fi maa n salaye oro okan won fun eni ti won ba a ba soro. Apeere:
  2. Ki ile to pa osika, ohun rere a ti baje
  3. A ku to eni bog be ki a maa to oro ba nii so.
  4. Agba to n sare ni aarin oja ni bi nkan ko le, a je pe o n le nkan
  5. Agbatan ni a n gba ole, bi a ba da so fun ole a paa laro, bi a ba la ole nija, a sin-in dele.
  6. Ara aimuole le n ko je ki a mop e ologbo n sode.
  7. OWE FUN IBAWI: Bi enikan ba n huwa ti ko dara, owe awon agba fi ma n ba iru eni bee wi. Apeere:
  8. Bi omode ba n se bi omode, agba o si se bi agba.
  9. Aja kii roro ko so oju lo meji
  10. Afase gbe ojo n tun ara re je
  11. Adiye funfun ko mo ara re la gba
  12. A kii roe ran enu lori, ki a tun maa fi ese wa ire nile

 

  1. OWE FUN IKILO: Ti a ba se akiyesi pe enikan wa ninu ewu ti oun gan-an ko mo tabi fura, awon agba maa n pa owe lati kiilo fun pe ki osora. Apeere:
  2. Bi eti ko ba gbo yinkin, inu kii baje
  3. Ise ni oogun i se
  4. Alaso ola kii ba elepo sere
  5. Agboju logun fi ara re fun osi ta
  6. Ese gin nile origafe, arijose ku, a ko ri enikan

 

  1. OWE FUN ISIRI: A maa n lo awon owe yii lati tu eniyan ti o wa ninu ibanuje ninu tabi eni ti o ti so ireti nu oro aye re. Bi apeere:
  2. Igbeyin ni alayo n ta
  3. Kii buru titi ki o ma ku enikan mo ni, eni ti yoo kun i a komo
  4. Ajeji owo kan ko gberu dele
  5. Ise kii se ni, ki omo eni maa dagba
  6. Pipe ni yoo ope, akololo a pe baba

 

Ise Asetilewa

Se alaaye ati itunmo owe yii “Adiye funfun ko mo ara re lagba”.

 

See also

AKORI EKO: IHUN ORISIIRISII AWE GBOLOHUN PO DI ODIDI GBOLOHUN

OSE KEFA ETO IGBEYAWO ABINIBI

ORISII ONA TI A N GBA SOGE NILE YORUBA

ETO ISELU ODE-ONI

ETO ISELU ABINIBI ATI ODE ONI

Leave a Comment

Your email address will not be published. Required fields are marked *