Ninu oro ‘baba’ ege meji ni a ni: ‘ba-ba’. Ege kookan ni o ni iro faweli ati ami ohun. Ege kookan yii ni a n pe ni silebu.
ABUDA SILEBU
(i) Silebu le je iro faweli kan tabi iro konsonanti ati faweli. Apeere:
i – ya
ba – ba
ko – bo
e – gbon
(ii) Iye ibi ti ohun ba ti je yo ninu oro kan ni yoo fi iye silebu ti oro naa ni han. Bi apeere:
Ife – Ibi meji ni ohun ti je yo (Silebu meji)
Omuti – Ibi meta ni ohun ti je yo (Silebu meta)
Ikadii – Ibi merin ni ohun ti je yo (Silebu merin)
IHUN SILEBU
Apa meji ni silebu pin si. Awon ni:
- Odo silebu
- Apaala silebu
(i) Odo Silebu: Odo silebu ni ipin ti a maa n gbo ketekete ti a ba pe ege silebu kan. Ori re ni ami ohun n wa. Iro faweli tabi konsonanti aranmu asesilebu ‘n’ ni won le je odo silebu. Odo silebu ni a fala si nidii wonyi:
i-wa
i-gba-la
o-ro–n-bo
(ii) Apaala Silebu: Awon iro ti a ki i gbo ketekete ti a ba pe oro sita. Konsonanti inu silebu ni o maa n duro bii apaala silebu. Apaala silebu ni a fala si nidii wonyi:
i-wa
o-san
du-n-du
EYA IHUN SILEBU
(i) Silebu Onifaweli Kan (F): Eyi le je eyo faweli kan soso. Apeere iro faweli bee ni a fala si nidii wonyi:
A ti lo
Mo ri o
Mo ka a
Gbogbo iro faweli wonyi le da duro bii silebu:
a, e, ҿ, i, o, ϙ, u,
a, e, ҿ, i, o, ϙ, u,
a, e, ҿ, i, o, ϙ, u,
(ii) Silebu Alahunpo Konsonanti ati Faweli (KF). Apeere iru silebu bee ni wonyi:
wa, ba, bϙ, bҿ, ri, ra, mo, kϙ
gbϙn, ran, tan, rin, kun, wϙn
(iii) Konsonanti aranmupe asesilebu (N). Apeere iru silebu bee niyi:
n lϙ
o-ro-n-bo
i-sa-n-sa
PINPIN ORO SI SILEBU
Awon oro kan wa ti won ni ju silebu kan lo ninu ihun. Awon oro bee ni a pe ni ‘oro olopo silebu’. Apeere:
(i) Oro Onisilebu Meji
Oro | Ipin | Ihun | Iye silebu |
ҿgbon
ifҿ iku Bϙla |
Ҿ-gbon
i-fҿ i-ku Bϙ-la |
f-kf
f-kf f-kf kf-kf |
meji
meji meji meji |
(ii) Oro Onisilebu Meta
Oro | Ipin | Ihun | Iye silebu |
Idoti
Agbado Ijangbon Kansu Gbangba Banjo Gende Gbolahan |
I-do-ti
a-gba-do i-jan=gbon ka-n-su gba-n-gba Ba-n-jo Ge-n-de Gbo-la-han |
f-kf-kf
f-kf-kf f-kf-kf kf-n-kf kf-n-kf kf-n-kf kf-n-kf kf-kf-kf |
meta
meta meta meta meta meta meta meta |
(iii) Oro Onisilebu Merin:
Oro | Ipin | Ihun | Iye silebu |
Ekunrere
Alangba Opolopo Olatunji Mofiimu Ankoo Laaro |
e-kun-re-re
a-la-n-gba o-po-lo-po O-la-tun-ji Mo-fi-i-mu a-n-ko-o la-a-a-ro |
f-kf-kf-kf
f-kf-kf-kf f-kf-kf-kf f-kf-kf-kf kf-kf-f-kf f-n-kf-f kf-f-f-kf |
merin
merin merin merin merin merin merin |
(iv) Oro Onisilebu Marun-un
Oro | Ipin | Ihun | Iye silebu |
Alaafia
Ogunmodede Ogedengbe Alagbalugbu Agbalajobi Nigbakuugba |
a-la-a-fi-a
o-gun-mo-de-de o-ge-de-n-gbe a-la-gba-lu-gbu a-gba-la-jo-bi ni-gba-ku-u-gba |
f-kf-f-kf-f
f-kf-kf-kf-kf f-kf-kf-kf-n-kf f-kf-kf-kf-kf f-kf-kf-kf-kf kf-kf-kf-f-kf |
marun-un
marun-un marun-un marun-un marun-un marun-un |
(v) Oro Onisilebu Mefa
Oro | Ipin | Ihun | Iye silebu |
Gbangbayikita
Orogodoganyin Afarajoruko Alapandede Konsonanti Bookubooku |
Gba-n-gba-yi-ki-ta
o-ro-go-do-gan-yin a-fa-ra-jo-ru-ko a-la-pa-n-de-de ko-n-so-na-n-ti bo-o-ku-bo-o-ku |
kf-n-kf-kf-kf-kf
f-kf-kf-kf-kf-kf f-kf-kf-kf-kf-kf a-kf-kf-n-kf-kf kf-n-kf-kf-f-kf kf-f-kf-kf-f-kf |
mefa
mefa mefa mefa mefa mefa |
ISE AMUTILEWA
- (a) Ki ni Silebu? (b) So abuda silebu meji ti o mo pelu apeere
- Ko apeere oro marun-un ti o ni konsonanti aranmupe asesilebu. Pin won si iye silebu.
- Pin awon oro wonyi si iye silebu won:
(i) Akalamagbo (ii) Olododo (iii) Aworerin-in (iv) Akikanju
(v) Osoosu (vi) egbeegberun (vii) ileladewa (viii) igbaradi
(ix) iyaloosa (x) Akerefinusogbon
See also
AKORI EKO: AROKO AJEMO – ISIPAYA
AKORI EKO: ATUNYEWO AAYAN OGBUFO