Kin – in – ni awe gbolohun?
Awe gbolohun ni ipede to ni oluwa ati ohun ti oluwa se
Bi apeere:
Ayinke mu omi
Adepoju ti jeun
Kasali je eba
Awe gbolohun le je ipede ti ko ni ju apola oro oruko ati apola kookoo lo. Apeere:
Mo gba ebun naa
Awon ni won wa
Ade ti sun lanaa
Mo gba ebun naa
apola apola oro – ise
oro-oruko (verb phrase)
(Noun phrase)
Awe gbolohun le da duro ki o ni itumo. Apeere:
Isola ati Ajani ra aso
Omi ero naa mo
Awe gbolohun miiran le da duro ki maa ni itumo (awe gbolohun afarahe)
Ti a ba ko ile
Iba ke si mi
Yala o wa tabi ko wa
Awe gbolohun le da duro bi odidi gbolohun, iru awe gbolohun bee ni a maa pe ni olori awe gbolohun. Apeere:
Won gba
Ade mo
Iya omo ni
Itesiwaju ise lori awe gbolohun Abeke gbon
Opolopo awon gbolohun abode ni o le se ise awe gbolohun. Sugbon kii se gbogbo awe gbolohun lo le da duro bii gbolohun. Awon gbolohun isale wonyi le se ise awe gbolohun.
Akanmu mu emu
Apinke se iresi
Ode pa igala
Orisii awe gbolohun (Types of clause)
- Olori awe gbolohun (main clause): Eyi maa n da duro, o si maa n ni itumo ati paapaa o maa n sise odidi gbolohun. O ti ihun jo gbolohun abode tabi gbolohun eleyo oro-ise. Bi apeere:
Awon omode feran iresi
Aja Ogundeji ku
Ise dara
- Awe gbolohun afarahe (subordinate clause): Inu ihun gbolohun olopo oro-ise tabi gbolohun onibo ni a ti maa n ri awe gbolohun afarahe. Ninu gbolohun olopo oro – ise. Ipa kan yoo je gbolohun kikun nigba ti awon iyoku yoo je awe gbolohun afarahe ti ko ni itumo.
Orisii awe gbolohun afarahe
- Awe gbolohun afarahe asapejuwe: ti ni atoka ibeere awe gbolohun yii. Awe gbolohun yii maa n tele oro oruko tabi apola oruko, o maa n je ki a mo nipa apejuwe nkan. Bi apeere
Apinke ti o sun ti dide
Aso Ankara ti mo ra dara
Omoge ti mo n soro re niyi
- Awe gbolohun afarahe asodoruko: ‘Pe’ ni o maa n bere awe gbolohun yii, o le sise oluwa ati abo, o si maa n sise iso – doruko ninu ihun gbolohun. Apeere:
Pe Olu ku ti mo gbo igbe ni mo fi ta
Pe oju ka awon ole naa mo dun mo mi
Oda mi loju pe omo naa ko le jale
iii. Awe gbolohun afarahe asaponle: Awon oro atoka fun awe gbolohun yii n ‘nigba’, ‘ti’, ‘nitori ti’ abbl. Awon oro – ise ti won maa n tele gbolohun ni won maa n pon. Bi apeere:
Aja naa ku nigba ti oko ko lu u
Emi yoo lo nisinsinyii ti mo gbo pe won de
Ole naa ku nigba ti olopaa kolu won
Obrinrin naa ku nitori ko ri owo le iwosan san
Iyato ti o wa laarin apola ati awe gbolohun (Differences between phrase and clause)
APOLA (PHRASE) | AWE GBOLOHUN (CLAUSE) |
1. Apola kii ni oro – ise (ayafi ninu apola ise) Bi apeere:
Iya Joke Aburo Badejo Ni Ibadan |
Awe gbolohun gbodo ni oro – ise ninu. Bi apeere:
Ki o to sun Ti mo ra Maa jo |
2. Apola ko le da duro ki o fun wan i itunmo kikun. Bi apeere:
Ni abule odu Papa asafa Aja ode Rin kemokemo |
Olori awe gbolohun le da duro ki o fun wan i itumo kikun. Bi apeere:
Mo ti de Fijobi kan ilekun Aso Ankara dara |
3. Apola ko le daduro bi odidi gbolohun kikun. Bi apeere:
Iwo ati emi Ni Osogbo Ti ile bo |
Olori awe gbolohun le da duro bii gbolohun kikun ti o ni itumo. Bi apeere:
Obinrin yii burewa Egungun ko korin Adeojo kii ja |
See also
OSE KEFA ETO IGBEYAWO ABINIBI
ORISII ONA TI A N GBA SOGE NILE YORUBA
ETO ISELU ABINIBI ATI ODE ONI