Ibanisoro ni ona ti eniyan meji tabi ju bee lo n gba fi ero inu won han si ara lona ti o fi ye won yekeyeke. Ona yii ni a n pen i ede. Ede ni o n fun ohun ti a n so ni itumo. Bi eni meji ti won ko gbo ede ara ba n soro, bi ariwo lasan no ohun ti won n so.
Ni aye atijo, awon baba-nla wa kii fi gbogbo enu soro. Won gba wi pe ‘gbogbo aso ko la n sa loorun’. Awon ona kan wa ti won n gba ba eni to sun mo won, to wa nitosi tabi ona jijin soro lai lo enu. Se “Asoku oro ni je omo mi gb’ena”. Won a maa lo eya ara tabi fi nnkan miiran paroko ranse si won, ti itumo ohun ti won soyoo si ye won.
Ni ode-oni ewe, irufe ona ibanisoro yii wa, bi o tile je wi pe ona igbalode ni won n gbe e gba. Gbogbo nnkan wonyi ni a o yewo finnifinni.
IBANISORO AYE ODE ONI
Ni ode-oni, ede ni opomulero ona ibanisoro. Ede ni a fi n se amulo agbara lati ronu ti a o si so ero inu wa jade fun agboye: ti a fi n salaye ohunkohun. Ohn ni a fi n ba ni kedun, ti a n fi n ban i yo, ohun ni a fi n ko ni lekoo ni ile ati ile-iwe. Ede ni a fi n gbani ni iyanju, ti a tun fi n danilaraya. Pataki ede ni awujo ko kere.
Bi ko bas i ede, redio, iwe iroyin ko le wulo. Ede ni redio ati telifison fi n danilaraya, ti won fi n ko ni lekoo, ti won fi n royin. Olaju esin ati ti eko imo sayensi ti mu aye lu jara nipa imo ero. Awon ona ibanisoro ode oni niwonyi:
- Iwe Iroyin: Ipa pataki ni iwe iroyin n ko bii ona ibanisoro. Henry Town send ni o koko te “Iwe Iroyin fun awon Egba ati Yoruba” jade ni ede Yoruba ni odun 1859. Eyi ni iwe iroyin akoko ni ede Yoruba. Leyin re ni “Iwe Irohin Eko” ti A.M. Thomas je olootu re jade ni odun 1888. Odun 1891 ni Eni-owo J. Vernal gbe “Iwe Eko” jade. Eyi fi han wipe ojo iwe iroyin tip e ni ile Yoruba.
- Telifison: Ile Yoruba naa ni Telifison akoko ni ile eniyan dudu ti bere ni ilu Ibadan. Bi oruko re “Ero-Amohun-Maworan” ni a n pe o. anfaani gbigbo oro ati riri aworan awon eniyan inu re wo je iranlowo ti ko ni afirwe ninu gbigbe ede ati asa Yoruba laruge. Ona kaan naa niyi ti a fi gbe ero eni si ori eto, ti ibanisoro si n waye.
- Redio: Ojo redie naa tip e ni ile Yoruba. Bii oruko re ‘ero-asoromagbesi’, oro lasan ni a n ti won n so ni ori eto okan-o-jokan won. Anfaani wa fun eniyan lati gbe ero won si ori afefe lati fi danilaraya, ko ni lekoo, ni lekoo ati fi laniloye.
- Pako Alarimole lebaa Titi ati Ina Adari-Oko: Awon patako alarimole wa kaakiri oju popo ti won n juwe tabi dari eni si opopona laarin ilu-nla-nla. Bee ni ina adari-oko wan i ojuu Popo ti won n dari oko. Awon meta ni awon fi n paroko lilo ati diduro oko ni ikorita. Awo pupa duro fun ‘duro’, ewu wa lona; awo olomi osan ni ki a si ina oko ni imura sile lati lo, bee ni awo ewe ni ki oko maa lo.
- Ero-Aye-Lu-Jara: (Intaneeti). Ero ayelujara je gbagede agbaye to si sile fun teru-tomo, ti a le lo, to si wan i arowoto gbogbo eniyan.
- Leta Kiko: Leta kiko je aroko aye atijo ni orisiirisii ona. Gbigbe ni a n gbe leta, gbigbe naa ni a n gbe aroko ti a ba di ni gbinrin, titu ni a n tu apo-iwe lata, titu naa ni an tu gbinrin ti a di, kika la n ka leta, wiwo ni a n ami aroko. Igba ti won bat u u ni won yoo to mo ohun to wa nibe.
- Foonu: Oro naa ni a n so si inu foonu ti eni to wan i odikeji ti a pe n gbo. Bi oun naa ba fesi awa ti a pe naa yoo gbo. Ona ibanisoro yii di ilumoka ni ile Yoruba. A le wan i Eko, ki a ma takuroso pelu eni to wan i ilu Oyinbo!
- Agogo: Bi o tile je pe agogo je ohun-elo iparoko aye atijo, won si n lo won bi ona ibanisoro ni ode-oni. Bi apeere:
Agogo ile isin lilu – lati pe eeyan wa josin ni soosi
Agogo omo ile wa – lati fi pea won akekoo wole
Agogo onisowo – lati fi fa onibara won mora.
OSE KARUN-UN
AKORI EKO: ONKA YORUBA (EGBAA de AADOTA OKE)
Igba mewaa (200 x 10) ni a n pe ni egbaa. A le wa ka a bayii:
Onka Geesi | Onka Yoruba | Alaye ni Yoruba | Alaye ni Geesi |
2,000
4,000 6,000 8,000 10,000 12,000 14,000 16,000 18,000 20,000 |
Egbaa
Egbaaji Egbaata Egbaarin Egbaarun-un Egbaafa Egbaaje Egbaajo Egbaasan-an Egbaawaa (oke kan) |
Igba lona mewaa
Igba lona ogun Igba lona ogbon Igba lona ogoji Igba lona aadota Igba lona ogota Igba lona aadoje Igba lona ogoje Igba lona aadorun-un Igba lona ogorun-un |
2,000 x 1
2,000 x 2 2,000 x 3 2,000 x 4 2,000 x 5 2,000 x 6 2,000 x 7 2,000 x 8 2,000 x 9 2,000 x 10 |
E je ki a lo egbaa lati se onka nipa fifi egbaa pin iye onka ti a ba fe ka, ji a to maa kaa loke loke.
Onka Geesi | Alaye ni Geesi | Onka Yoruba | Alaye ni Yoruba |
30,000
32,000 34,000 36,000 38,000 42,000 44,000 46,000 48,000 52,000 54,000 56,000 58,000 |
2,000 x 15
2,000 x 16 2,000 x 17 2,000 x 18 2,000 x 19 2,000 x 21 2,000 x 22 2,000 x 23 2,000 x 24 2,000 x 26 2,000 x 27 2,000 x 28 2,000 x 29 |
Egbaa meedogun
Egbaa merindinlogun Egbaa metafinlogun Egbaa mejidinlogun Egbaa mokandinlogun Egbaa mokanlelogun Egbaa mejilelogun Egbaa metalelogun Egbaa merinlelogun Egbaa merindinlogbon Egbaa metadinlogbon Egbaa mejidinlogbon Egbaa mokandinlogbon |
Egbaa lona meedogun
Egbaa lona merindinlogun Egbaa lona metadinlogun Egbaa lona mejidinlogun Egbaa lona mokandinlogun Egbaa lona mokanlelogun Egbaa lona mejilelogun Egbaa lona metalelogun Egbaa lona merinlelogun Egbaa lona merindinlogbon Egbaa lona metadinlogbon Egbaa lona mejidinlogbon Egbaa lona mokandinlogbon |
‘o din’ tabi ‘o le’ ni a o maa lotiti de ori onkaye ta a n fe. Bi apeere: 30,400 je egbaa meedogun o la irinwo, 51,000 ni egberundilogbon; 57,991 je egbaa mokandinlogbon o din mesan-an; 58,008 je egbaa mokandinlogbon o le mejo. Lati ori 20,000, a le wa ma aka oke bayii:
Onka Geesi | Alaye ni Geesi | Onka Yoruba | Alaye ni Yoruba |
40,000
60,000 80,000 100,000 120,000 140,000 160,000 180,000 200,000 220,000 240,000 260,000 280,000 300,000 400,000 500,000 600,000 800,000 1,000,000 |
20,000 x 2
20,000 x 3 20,000 x 4 20,000 x 5 20,000 x 6 20,000 x 7 20,000 x 8 20,000 x 9 20,000 x 10 20,000 x 11 20,000 x 12 20,000 x 13 20,000 x 14 20,000 x 15 20,000 x 20 20,000 x 25 20,000 x 30 20,000 x 40 20,000 x 50 |
Oke meji
Oke meta Oke merin Oke marun-un Oke mefa Oke meje Oke mejo Oke mesan-an Oke mewaa Oke mokanla Oke mejila Oke metala Oke merinla Oke meedogun Ogun oke Oke marundinlogbon Ogbon oke Ogoji oke Aadota oke |
Oke lona meji
Oke lona meta Oke lona merin Oke lona marun-un Oke lona mefa Oke lona meje Oke lona mejo Oke lona mesan-an Oke lona mewaa Oke lona mokanla Oke lona mejila Oke lona metala Oke lona merinla Oke lona meedogun Oke lona ogun Oke lona marundinlogbon Oke lona ogbon Oke lona ogoji Oke lona aadata |
Bi a se n lo ‘o din’ ni kika egbaalegbaa naa ni a n lo ‘o din’ ati ‘o le’ ti a ba n ka lokeelokee. Bi apeere:
Onka Geesi | Alaye ni Geesi | Onka Yoruba | Alaye ni Yoruba |
20,080
40,008 40,060 43, 000 47,000 49,000 51,000 55,000 57,000 59,000 |
20,000+1 = 80
20,000+2 = 8 20,000×2 + 60 20,000×2 + 3,000 20,000×2 + 7,000 20,000×2 + 9,000 20,000×2 + 11,000 20,000×2 + 15,000 20,000×2 + 17,000 20,000×2 + 19,000 |
Orin le l’oke kan
Oke meji le mejo Otalelokee meji Oke meji le legbeedogun Oke meji le leeedegbaarin Oke meji le eedegbaarun-un Oke meji o le eedegbaafa Oke meji o le eegbaajo Oke meji o le eedegbaasan-an Oke meji le eedegbaawaa |
Oke kan o le ogorin
Oke meji ati eeyo mejo Oke meji o le ogota Oke meji ati egbeedogun Oke meji ati eedegbaarin Oke meji ati egbaarun-un Oke meji ati egbaafa o din egberun Oke meji ati edegbaajo Oke meji ati eedegbasan Oke meji ati eedegbawa |
ISE AMUTILEWA
- Ko onka awon figo wonyi:
- 30,000
- 35,000
- 36,000
- 47,000
- 52,000
- 600,000
- 750,000
- 850,000
- 950,000
- 1,000,000
See also
AKORI EKO: AROKO ONI-SORO-N-GBESI