AKOLE ISE: ATUYEWO AWON EYA ARA – IFO (EYA ARA ISORO)
Eya ara ifo ni eya ara ti a maa n lo fun gbigbe iro ifo jade
A le pin eya ara ifo si isori meji, awon ni;
- Eya ara ifo ti a le fi oju ri: apeere: ete oke, ete isale, eyin oke, e yin isale, evigi, aja enu, iwaju a lo n, aarin lion, eyin ahon, afase, ita gongongo, olele, aja-enu, kaa imu
- Eya ara ifo ti a ko le fi oju ri: Apeere; Edo-foro, komookun, eka-komookun, tan-an-na, inu gogongo, kaa ofun.
AWON EYA ARA TI A FI N PE IRO EDE
AFIPE: Afipe ni gbogbo eya ara ifo ti won kopa ninu pipe iro ede jede. A le pin awon afipe wonyi si meji; awon nii
- APIPE ASUNSI: Eyi ni afipe ti o le gbera nigba ti a aba n pe iro won maa n sun soke sodo ti aban soro. Apeere; Afipe asunsi ni, Ete Isale, Eju isale, iwaju alion, aarin alion, eyin ahon, olele.
- AFIPE AKANMOLE: Eyi ni awon afipe ti ko le gbara soke sugbon ti won maa n duro gbari bi a ba n pe iro jade. Apeere afipe akonmole ni, ete oke, aja-enu, afase, iganna ofun, eyin oke, erigi, olele.
Ipo ti ahon ati ete wa ninu pipe faweli ede Yoruba
- IPO AHON: Nigba ti a ba pe iro faweli, ape kan ara ahon maa n gbe soke ti yoo su ike ninu enu
A le pin ahon si isori meta ninu pipe iro jade. Awon ni;
- Faweli waju: Eyi ni faweli ti a pe nigba ti iwaju ahon gbe soke ju lo ninu enu awon faweli naa ni,I,e,e,in,en.
- Faweli aarin: Eyi ni faweli ti a pe nigba ti aarin gbe soke ju lo ninu enu. Awon ni, a, en.
- Faweli eyin: Faweli eyin ni faweli ti a pe nigba tie yin ahon gbe soke ju lo ninu enu, awon faweli naa ni, u, o,o,un,on.
- IPO ETE: Ipo meji ni ete le wa bi a ba n pe iro faweli. Ete le te perese tabi ki o su roboto.
Faweli perese: Eyi ni faweli ti a gbe jade nigba ti ete fe seyin ti alafo gigun tin-in-rin wa laarin ete memeeji. Awon faweli naa ni, a,e,e,I,an,en,in.
Faweli roboto: Eyi ni awon faweli ti a gba jade nigba ti ete ka roboto. Awon ni, o,u,o,un,on.
EKA ISE: ASA
AKOLE ISE: EKO ILE- ASA IKINI
Eko ile ni eko iwa hihu: iwa rere, iwa to to, iwa to ye ti obi fi n ko omo lati kekere.
Eko ile je iwa omoluabi, ati kekere ni iru eko yii ti n bere ti yoo si di baraku fun omo titi ojo aye re.
Dandan ni fun omo lati mo bi ati n ki baba, iya ati awon miran ti o ju ni lo ni gbogbo igba.
Ikini akoko / igba.
IGBA / AKOKO | IKINI | |
I | Ojo | Eku ojo / otutu |
Ii | Oye | Eku oye |
Iii | Iyan | Eku aheje kiri o |
Iv | Ni owuro | Ekaa oro |
V | Ni osan | Ekaa san |
Vi | Ni irole | Eeku irole |
Vii | Ni oru | Ekuaajin |
Ikini akoko Ise
ISE | IKINI | IDAHUN | |
I | Agbe | Aroko bodu de o | Ase |
Ii | Onidiri | Oju gbooro, eku ewa | Iyemoja |
Iii | Babalawo | Aboru boye, sboye bo sise | Amin |
Iv | Awako | Oko a re foo, goun a pana mo o | Amin o |
V | Akope | Igba a ro o | O o |
Vi | Osise ijoba | Oko oba ko ni sa yin lese | Ase |
Viii | Iya oloja | Aje a wo gba o | Ase |
EKA ISE: LITIRESO
AKOLE ISE: ATUYEWO ORISIRISI EYA LITIRESO
Litireso ni akojopo ti a fi oro ni ede kan tabi ti e ko sile.
Isori litireso
- Litireso alohun (atenudenu)
- Litireso apileko (alakosile)
Litireso alohun: Eyi ni awon ewi ti a jogun lati enu awonn babanla wa.
Ohun enu ni a fi n gbe litireso jade, ko si ni akosile rara.
Litireso alohun kun fun o gbon imo ati oye agba, nigba ti imo moo ko moo-ke ko ti de ile wa ohun ni awon baba nla wa n lo ninu igbo ke gbodo won.
Litireso alohun pin si ona meta
- ewi
- oro geere
- ere onise.
Litireso apileko : Eyi ni litireso ti a se akosile nigba ti imo mooko-mooka de ile wa.
Litireso yin je litireso alakosile.
Litireso alohun ni ategun tabi orison litireso apileko
Isori litireso apileko ni wonyi,
a.ewi
- Ese-onitan
- itan aroso.
Igbelewon:
- Fun eya ara ifo loriki
- Pin eya ifo si isori
- Salaye awon eya ara ti a fi n pe iro
- Kin ni litireso?
- Salaye isori litireso
- Fun eko ile loriki
Ise asetilewa: bawo ni a se n ki awon wonyi ni ile Yoruba:
- Oba
- Ontayo
- Alaboyun
- Ijoye ilu
- Iya olomo tuntun
- Akope
See also
AKORI EKO: ITESIWAJU AWON ORISA ILE YORUBA