Oro Apejuwe:-Eyi ni awon oro ti o n toka isele inu gbolohun .
Oro oruko ni o maa n yan.
Ise oro Apejuwe
- O le se ise eyan ninu gbolohu
(a) Oro apejuwe le yan oro – oruko ni ipo oluwa. Apeere;
– Oruko rere san ju wura oun fadaka lo
– Iwa bukuku ko ye eniyan
(b) Oro apejuwe le yan oro-oruko ni ipo abo. Apeere;
– Inioluwa la igi gbigbe
– Ayinde wo aso funfun
- A le seda oro apejuwe lati ara oro-ise. Apeere;
Oro Ise Oro apejuwe ti a seda
- ga giga
- le lile
iii. sun sisun
- fe fife
- ka kike
akiyesi:- A le se atenumo awon oro apejuwe wonyi ninu gbolohun. Apeere;
(a) Ere lile lile ni Bolu n se
(b) Ibi giga giga ni mo n lo
- Oro apejuwe n se ise atenumo:- A le gbe oro apejuwe yi saaju oro oruko to yan lati fi se atenumo. Apeere;
(a) Omugo omo ko dara
(b) Agbere aya ko sun won
(d) Ako okuta ni a fin pa ekuro
ORO-APONLE:- Oro aponle maa n fi kon itumo oro-ise ki o le ye nisi. Oro aponle maa n sise epon ninu gbolohun.
Isori oro Aponle:
(a) Oro-aponle pon-n-bele – Eyi ni oro aponle ti a ko seda. Apeere;
(i) Aso re mo toni
(ii) Yemi pupa foo
(iii) ile ga gogoro
(b) Oro aponle ti a seda:- Eyi ni oro aponle ti a seda o maa n se ise apetunpe oro aponle pon-n-bele. Apeere;
Oro aponle pon-n-bele oro aponle ti a seda
Toni tonitoni
Were werewere
Lau laulau
Rako rakorako abbl.
Ise oro aponle ninu gbolohun
- O maa n toka si isesi; Apeere
(a) Olu yo kelekele wo ile
(b) Omo naa n rin jauajau
- O maa n toka siohun kan ti a n se to ti de gongo (climax).
(a) Oko naa jona raurau
(b) Adupe je ounje naa patapata
(d) Ile naa wo womuwomu
- O maa n toka ibi kan pato ti isele ti wa ye;
(a) Awon ologin sa pamo sinu igbo
(b) Remileku se igbeyawo ni ile ijosin
(d) Jolade lo ki kabiyesi ni aafin
- O n toka idi ti isele fi n se.
(a) A n sise kia a le lowo lowo
(b) Sade ko kawe nitori ko lowo
(d) Obi n to omo ki won le fun won ni isinmi abbl.
- A n lo oro aponle lati fi irisi nnkan han. Apeere;
(a) Osupa naa mole rokoso
(b) Ina naa n wo rakorako
Igbelewon:–
Ko ise oro apejuwe ati oro aponle mejimeji pelu apeere;
Ise Asetilewa: Yoruba akayege iwe Amusese fun ile eko sekondiri kekere iwe kin-in-ni lati owo o L. Orimogunje, K. Adebayo, F. Okiki. Oju iwe kerindinlogun Eko ketala
Ede:- Onka ni ede Yoruba (ookan-lelogoorun-un de igba) 101-200
Onka Yoruba ni ona ti a n gba ka nnkan ni ona ti yoo rorun.
101 – Ookanlelogorun-un
102 – Ejilelogorun-un
103 – Eetalelogorun-un
104 – Eerinlelogorun-un
105 – Aarundinlaadofa
106 – Eerindinlaadofa
107 – Eetadinlaadofa
108 – Eejidinlaadofa
109 – Ookandinlaadofa
110 – Aadofa
111 – Ookanlelaa-adofa
112 – Eeejilelaa-adofa
113 – Eetalelaa-adofa
114 – Eerinlelaa-adofa
115 – Aarundinlogofa
116 – Eerindinlogofa
117 – Eetadinlogofa
118 – Eejidinlogofa
119 – Ookandinlogofa
120 – Ogofa
121 – Ookanlelogofa
122 – Eejilelogofa
123 – Eetalelogofa
124 – Eerinlelogofa
125 – Aarundinlaa-adoje
126 – Eerindinlaa-adoje
127 – Eetadinlaa-adoje
128 – Eejidinlaa-adoje
129 – Ookandinlaa-adoje
130 – Aadoje
131 – Ookanlelaa-adoje
132 – Eejilelaa-adoje
133 – Eetalelaa-adoje
134 – Eerinlelaa-adoje
135 – Aarundinlogoje
136 – Eerindinlogoje
137 – Eetadinlogoje
138 – Eejidinlogoje
139 – Ookandinlogoje
140 – Ogoje
141 – Ookanlelegoje
142 – Eejilelogoje
143 – Eetalelogoje
144 – Eerinlelogoje
145 – Aarindinlaa-adojo
146 – Eerindinlaaadojo
147 – Eetadinlaa-adojo
148 – Eejidinla-adojo
149 – Ookandinlaa-adojo
150 – Aadojo
151 – Ookanleladojo
152 – Eejilelaa adojo
153 – Eetalelaa-adojo
154 – Eerinlelaa-adojo
155 – Aarindinlogojo
156 – Eerindinlogojo
157 – Eetadinlogojo
158 – Eejidinlogojo
159 – Ookandinlogojo
160 – Ogojo
161 – Ookanlelogojo
162 – Eejilelogojo
163 – Eetalelogojo
164 – Eerinlelogojo
165 – Aarindinlaa-adosan-an
166 – Eerindinlaa-adosan-an
167 – Eetadinlaa-adosan-an
168 – Eejidinlaa-adosan-an
169 – Ookandinlaa-adosan-an
170 – Aadosan-an
171 – Ookanlelaa-adosan-an
172 – Eejilelaa-adosan-an
173 – Eetalelaa-adosan-an
174 – Eerinlelaa-adosan-an
175 – Aarundinlogosan-an
176 – Eerindinlogosa-an
178 – Eejidinlogosan-an
179 – Ookandinlogosan-an
180 – Ogosan-an
181 – Ookanlelogosan-an
182 – Eejilelogosan-an
183 – Eetalelogosan-an
184 – Eerinlelogosan-an
185 – Aarundinlaa-aadowa
186 – Eerindinlaa-adowaa
187 – Eetadinlaa-adowaa
188 – Eejindinlaa-adowaa
190 – Aadowa/igba-o-din-mewa
191 – Ookanlelaa-adowa
192 – Eejilelaa-adowa
193 – Eetalelaa-adowa
194 – Eerinlelaa-adowa
195 – Aarundin-nigba
196 – Eerindin-nigba
197 – Eetadin-nigba
198 – Eejidin-nigba
199 – Ookandin-nigba
200 – Igba
Igbelewon:-
(i) Kin ni onka?
(ii) Ka onka Yoruba lati ookanlelogoorun-un de igba.
Ise Asetilewa:- Yoruba akayege iwe Amusese fun ile eko sekondiri kekere iwe kin-in-ni lati owo o L. Orimogunje, K. Adebayo, F. Okiki. Oju iwe kewa Eko keje
See also:
ISE ORO ORUKO ATI ORO AROPO ORUKO NINU GBOLOHUN
AKOLE ISE- EDE: AROKO ATONISONA ONIROYIN (NARRATIVE ESSAY)
Oriki Ati Eya gbolohun ede Yoruba pelu apeere (sentence)
Ede:- Atunyewo orisirisi gbolohun ede Yoruba
Ede:- Akaye onisoro-n-gbesi
Very good
Thank you Olowokande