AKOONU:- Silebu ni ege oro ti o kere julo ti eemi le gbe jade leekan soso
Iye ohun ti o ba wa ninu oro ni iya silebu ti oro naa yoo ni.
Fun Apeere
Wa-je oro onisilebu kan nitori pe ami ohun kan ni o wa lori re.
I / we = 2
Ba / ta = 2
Ihun silebu:-
Ona meta Pataki ni ihun silebu pin si awon naa ni:-
- Ihun faweli kansoso
- Ihun to je konsonanti ati faweeli.
- Ihun to je konsonanti aranmupe-asesilebu.
- IHUN FAWEELI KAN SOSO
Eyi ni ihun to je faweeli kan soso ‘f’ ni a maa n lo fun ihun yii..fun apeere
I / we
A /a / lo
- IHUN TO JE APAPO KONSONANTI ATI FAWEELI:-
Eyi ni ihun ti o je konsonanti ati faweeli,faweeli yii le je aranmupe tabi airanmupe. ‘KF’ni a n lo fun ihun yii.fun apeere
Je
Kf
Wa gbin
Kf kf
Ra sun
Kf kf
iii.IHUN TO JE KONSONANTI ARANMUPE ASESILEBU:-
Eyi ni ihun silebu ti konsonanti aranmupe ‘n’ ati ‘m’ maa n dun gege bi silebu.
‘N’ ni a maa n lo fun ihun yii.
Fun apeere
Gba /n /gba =3
Ke / n /gbe =3
A / la / n / gba =4
Bi /m / bo.
Kf-N-kf
Oro olopo silebu-;eyi ni oro ti o ni ju silebu kan lo,o le je silebu meji,meta tabi ju bee lo.
ap
Oro ipin ihun iye
Ade a-de f-kf meji
Sugbon su-gbon kf-kf meji
Nnkan n-n-kan f-f-kf meta
Opolopo o-po-lo-po f-kf-kf-kf merin
Ogunmodede o-gun-mo-de-de f-kf-kf-kf-kf marun-un
Alapandede a-la-pa-n-de-de f-kf-kf-N- kf-kf mefa
IGBELEWON
- kin ni silebu?
- Daruko ihun silebu, ki o si salaye won pelu apeere.
IWE ITOKASI:
Adewoyin S.Y (2014) IMO, EDE, ASA ATI LITIRESO YORUBA fun ile eko girama agba S.S.2 Corpromutt Publisher Nig Ltd. O.I 53-57
ISE ABINIBI
Eni ise ni oogun ise
Eni ise n se ko ma b’Osun
Oran ko kan t’Osun
I baa b’Orisa
O dijo to sise aje ko to jeun.
Owuro lojo, ise ni a fii se ni Otuu’Fe. Kaakiri ile Yoruba ni won ti n fi owuro sise. Won gbagbo wi pe ise loogun ise. Eredi ti won fi ise won ni okunkundun ni yii. Se eni mu ise je ko sai ni ise je. Eni ni ko feran ise ni won n pe ni ole. Won a maa ni ole afajo. Ojo odun de ni oro n dun ole tori gbogbo egbe re ni o raso sugbon oun ko le ra. Lara ise abinibi ile yoruba ni: ise agbe ‘eyi to wopo ju laarin ise abinibi’ ode, awako oju omi, babalawo ……..
ORISII ISE AGBE
Agbe olokonla
Agbe alaroje
ORISII OKO
Oko akuro
Oko etile
Oko egan
Oko odan
OHUN ELO ISE AGBE
Oko, Ada, apere, …………..
IGBELEWON
Salaye ogbin ati ikore agbado.
IWE ITOKASI:
Adewoyin S.Y (2014) IMO, EDE, ASA ATI LITIRESO YORUBA fun ile eko girama agba S.S.2 Corpromutt Publisher Nig Ltd. O.I 136-150.
ATUPALE IWE ASAYAN
Atupale iwe asayan ti ijoba yan.
Salaye eda itan marun-un ninu iwe apileko
ISE ASETILEWA
- ohun ti o kere ju ti eemi le gbe jade leekan soso ni (A) akoto (B) oro (C) faweli (D) silebu.
- Silebu meloo ni o wa ninu ‘’olopaa’ (A) meji (B) meta (C) merin (D) mejo
- Ninu ‘iwe’ odo silebu ni (A) i (B) w (C) e (D) ko si odo silebu nibe.
- Ibi ti awon agbe maa n gbin nnkan si ni (A) oko (B) ile (C) oko (D) papa
- Awon agbe maa n lo ……. lati ka koko (A) oko (B) ibon (C) obe (D) ada.
APA KEJI
- Salaye odo silebu ati apaala silebu pelu apeere mejimeji.
- Fun awon wonyi ni apeere mejimeji: KFKF, KFKFKF, KFNKF, FKF, FKFKF
- Salaye lori ohun ogbin kan.
See also
AROKO AJEMO ISIPAYA
Ise oro – Apejuwe at oro-aponle ninu gbolohun
ISE ORO ORUKO ATI ORO AROPO ORUKO NINU GBOLOHUN
AKOLE ISE- EDE: AROKO ATONISONA ONIROYIN (NARRATIVE ESSAY)
Oriki Ati Eya gbolohun ede Yoruba pelu apeere (sentence)