AKOONU
A le seda oro-oruko nipa sise apetunpe. Apetunpe yii pin si ona meji: eyi ni apetunpe kikun ati elebe. A le se Apetunpe Kikun fun Oro-Oruko
Apeere:
Kobo + kobo = kobokobo
Odun + odun = odoodun
Ale + ale = alaale
Osu + osu = osoosu
Osan + osan = osoosan
Egbe + egbe = egbeegbe
A le se Apetunpe Kikun fun Oro-Ise alakopo mo oro-oruko
Apeere:
Wole + wole = wolewole
Gbomo + gbomo = gbomogbomo
Jedo + jedo = jedojedo
Dana + dana = danadana
Apetunpe Elebe
Nipa sise apetunpe elebe fun oro ise pelu oro-oruko. A o se apetunpe fun konsonanti oro-ise ki a to fi faweli kun un. Apeere
Je = jije
Lo = lilo
Ra = rira
Ko orin = kikorin
Se eda = S + i + se eda
So ooto = s + i + sooto
Sugbon bi konsonanti aranmu m/n ba pari oro-ise naa, faweli aranmu ‘in’ olohun oke ni o a fi kun apetunpe
Mo – m + in + mo = mimo
Mu – m + in + mu = mimu
Ni – n + i + ni = nini
Na = n + I + na = nina
Na omo = n + in + omo ninamo
Apetunpe onka
Meta + meta = metameta
Nipa sise akanpo oro-oruko
IGBELEWON
- Daruko awon ona ti a n gba seda seda oro-oruko pelu apeere marun-unmarun-un.
- Ge awon oro wonyi si mofiimu: omokomo, iyaale, ijekuje, isekuse, Durotimi, Olorun, Iyeegbe, Ileese, Kabiyesi, agbalagba, Opolopo.
IWE ITOKASI:
Adewoyin S.Y (2014) IMO, EDE, ASA ATI LITIRESO YORUBA fun ile eko girama agba J.S.2 Corpromutt Publisher Nig Ltd.
ONA IBANISORO ODE ONI
Ni ode-oni, ede ni opomulero ona ibanisoro. Ede ni a fi n se amulo agbara lati ronu ti a o si so ero inu wa jade fun agboye ti a fi n salaye ohunkohun. Ohun ni a fi n ba ni kedun. Awon ona ibanisoro ode oni niwonyi:
- Iwe Iroyin: IweIroyin fun awon Egba 1859, Iwe iroyin Eko A.M Thomas 1888, Iwe Eko Vernal J. 1891.
- Telifisan: eyi awon Yoruba n pe ni Ero-Amohun-Maworan. Anfaani gbigbo oro ati wiwo aworan maa n wa nibe.
- Redio: Yoruba a ma ape e ni Ero-Asromagbesi sugbon ni aye ode oni o ti n gba esi.
- Pako alarimole ni Egbe Titi tabi Adari Ina Oko: eyi ni won maa n ko apejuwe ona ibi kan si. Adari ina oko ni o maa n dari oko ni popo ati titi ijoba.
- Ero–Aye-Lu-Jara: ohun ni oloyinbo n pe ni ‘internet’ intaneeti eyi ni o gbode fun gbogbo eniyan lati ba eniyan soro ni kiakia.
- Leta Kiko: eyi je aroko ti a n ko si eniyan: orisii leta kiko meji ni o wa awon naa ni Leta gbefe ati leta aigbefe.
- Foonu: ohun ni ero alagbeka ti a fi n ba eniyan soro. Ohun ni o yara ju lati ba eniyan soro ni ibikibi.
- Agogo: aye atijo nikan ko ni won ti n lo agogo gege bi nnkan ibanisoro. Won n lo agogo ni ile isin, ni ile iwe ati ni oja ni odo awon ti o n ta oja.
IGBELEWON
- Ko orisii iwe iroyin marun-un ti o gbode ka ni ode oni.
- Iyato meji wo ni o wa laarin Redio ati Telifisan.
- Ko awon ona miiran meta ti a n gba ba ara soro lode oni.
IWE ITOKASI:
Adewoyin S.Y (2014) IMO, EDE, ASA ATI LITIRESO YORUBA fun ile eko girama agba S.S.2 Corpromutt Publisher Nig Ltd. o.i 160-163.
ATUPALE IWE ASAYAN
Atupale awon ilo-ede/akanlo-ede. Sise orinkinniwin won.
APAPO IGBELEWON
- Ko orisii iwe iroyin marun-un ti o gbode ka ni ode oni.
- Iyato meji wo ni o wa laarin Redio ati Telifisan.
- Ge awon oro wonyi si mofiimu: omokomo, iyaale, ijekuje, isekuse, Durotimi, Olorun, Iyeegbe, Ileese, Kabiyesi, agbalagba, Opolopo.
- Fa awon ona ede ogun (20) ti o ti jeyo ninu iwe apileko ti o n ka lowo.
ISE ASETILEWA
- Awon ona ti a le gba seda oro-oruko je (A) meji (B) meta (C) merin (D) mejo
- Ewo ni ki i sa ara won? (A) elo (B) imo (C) igbagbo (D) ilekile.
- Toka si eyi ti a ko seda ninu awon oro-oruko yii (A) owo ati aso (B) ijekuje ati omokomo (C) eto ati igbagbo (D) imo ati ije.
- Ge oro yii si mofiimu ‘opolopo’ (A) opo-lo-po (B) opo-n—opo (C) opo opo (D) opo ati opo.
- Ona ibanisoro ti ko ni anfaani aworan ni (A) redio (B) telifisan (C) intaneeti (D) faasi
APA KEJI
- Ko ona marun-un ti a n gba ba eniyan soro laye atijo pelu alaye.
- Ko ona meta miiran ti a ngba ba eniyan soro lode oni.
- Seda oro oruko meji nipase: apetunpe, akanmoruko, afomo ibere ati afomo aarin.
OSE KARUN-UN
ONKA (2,000-50,000).
Onka Geesi | Onka Yoruba | Alaye ni Yoruba | Alaye ni Geesi |
2,000 | Egbaa | Igba l-nz mewaa | 2,000 x 1 |
4,000 | Egbaaji | Igba l-nz ogun | 2,000 x 2 |
6,000 | Egbaata | Igba l-nz ogbon | 2,000 x 3 |
8,000 | Egbaarin | Igba l-nz ogoji | 2,000 x 4 |
10,000 | Egbaarun-un | Igba l-nz aadota | 2,000 x 5 |
12,000 | Egbaafa | Igba l-nz ogota | 2,000 x 6 |
14,000 | Egbaaje | Igba l-nz aadoje | 2,000 x 7 |
16,000 | Egbaajo | Igba l-nz ogoje | 2,000 x 8 |
18,000 | Egbaasan | Igba l-nz aadorun-un | 2,000 x 9 |
20,000 | Egbaawaa (=k1 kan) | Igba l-nz ogorun-un | 2,000 x 10 |
IGBELEWON
- Ko onka awon figo yii; 30,000, 35,000, 36,000, 47,000, 52,000.
IWE ITOKASI:
Adewoyin S.Y (2014) IMO, EDE, ASA ATI LITIRESO YORUBA fun ile eko girama agba S.S.2 Corpromutt Publisher Nig Ltd. o.i 69-72.
See also
ORI-ORO | SILEBU EDE YORUBA
AROKO AJEMO ISIPAYA
Ise oro – Apejuwe at oro-aponle ninu gbolohun