AKOLE ISE:- Ede:- Aroso Asotan/Oniroyinn
Aroso asotan ni a fi n so nipa isele ti a fi oju wa ri tabi awon isele ti a gbo lenu enikan.
Apeere Ori oro Aroso Asotan
- Ere boolu alafessegbe kan ti mo wo
- Ayeye ere onilejile ti o koja ni ile-iwe mi
- Isomoloruko omo egbon mi obinrin.
Igbelewon:-
- Kin ni aroso asotan
- So aroso lori isele kan ti o soju re
Ise Asetilewa:- So aroso lori isele kan ti o soju re
Asa: Asa ogun jija (WAR/CONFLICT)
“Oni koyi n pale ogun mo, edumare ma je ki o tenu mi bo”. Eyi je okan lara owe ti Yoruba maa n pa nipa ogun jija laye atijo
Ogun ni ija laarin awon eniyan kan ni ilu tabi orile-ede ti o fa lilo awon ologun ati nnkan ija ogun
Ogun jija a maa wopo laarin awon Yoruba laye atijo nitori pe oun ni i fi ilu alagbara han yato si ilu ti ko ni agbara
- Awon ohun ti o n fa ogun
- Emi ilara
- Ija lori aale ile
- Gbigbija ilu ti a ni ife si
- Sisigun lati fi wa owo bi ode owo ba fe da ni
- Aayan ati ko dukia jo
- Fifi agidi je oye idile ti ko to si ni
- Yiye adehun lori isakole
- Ojukokoro si oro ile atirandiran tabi nnkan ti ki i se teni
- Obirin gbigba lona iwosi
- Owo ayaasan
- Efe ako ni dii ayo tita
- Sisigun lati fi ko ilu tabi ileto kan logbon
- Ija fun igi owo bi koko, o pe, orogbo, ataare abbl.
Awon Oloye Ogun
- Oranmiyan ni o de eto ati oye awon eso sile, oun ni eso kin-in-ni
- Olugbon
- Arese
- Onikoyi
- Olofa
- Balogun ootun, osi, asipa, ekerin, ekarun-un, abese, maye, ekefa, agbakin, aare, ikoleba, asaaju, ayingun, aare ago, jaguna, aare egbe omo Balogun.
- Aare onibon
- Seriki abbl.
Igbelewon :-
- Salaye eto ogun jija ni soki
- Ko ohun ti o le fa ogun marun-un
- Se akosile awon oloye ogun
Ise asetilewa :- yoruba Akayege iwe amusese fun ile eko sekondiri kekere iwe keji lati owo L. Orimogunje, K. Adebayo, F. Okiki(2012) Oju Iwe kin-in-ni Eko kin-in-ni
LITRESO:- KIKA IWE ESE-ONISE TI IJOBA YAN.
See also
OSE KETA (DISCRIPTIVE ESSAY)
AKOLE ISE: EDE :AROSO ALAPEJUWE
Eto ise fun saa keji
ASA IGBEYAWO
AKORI EKO: EYAN