AKORI EKO: ATUNYEWO APEJUWE IRO KONSONANTI ATI IRO FAWELI
Iro konsonanti ni awon iro ti idiwo maa n wa fun eemi ti a fi n gbe won jade.
Idiwo le waye nipa ki ona eemi se patapata, ki iro jade pelu ariwo taki ki o se die ki iro jade ni irorun. Awon iro konsonanti ede Yoruba ni:
d, b, f, g, gb, h, j, k, l, m, n, p, r, s, ṣ, t, w, y.
ABUDA IRO KONSONANTI: Ti a ba fe se apejuwe iro konsonanti nipa abuda, a nilati wo awon ilana wonyi wo ni okookan:
- Orison eemi ti a fi n pe iro
- Irufe eemi ti a lo
- Ipo alafo tan-an-na
- Ipo afase
- Irufe afipe ti a lo
- Irufe idiwo ti o wa fun eemi
Orisun eemi ti a fi pe iro: A nilati so orison eemi ti a lo lati pe iro konsonanti, yala
- Eemi edo-foro lati inu edo-foro ni tabi
- Eemi amisinu ti a seda re wa ni enu
Eemi edo-foro ni a fi n gbe gbogbo konsonanti ayafi iro /kp/ ati /gb/ ti a n lo apapo eemi edo-foro ati eemi ti a seda re wa ni enu.
Irufe eemi ti a fi gbe iro jade: A nilati so iru eemi ti a fi gbe iro konsonanti jade: Yala
- Eemi amisode;
- Eemi amisinu; tabi
- Apapo eemi mejeeji (bi o se ri ti a ba pe iro /kp/ ati /gb/)
Ipo alafo tan-an-na: A nilati so ipo tan-an-na ofun wa boya
- Ipo imi (fun iro aikunyun) tabi
- Ipo ikun (fun iro akunyun)
Ipo ti afase wa: A nilati so boya
- Afase gbera soke di kaa imu ni tabi
- Afase wale fun eemi lati gba kaa enu ati imu jade leekan naa.
Irufe afipe ti a lo: A nilati fi han boya
- Afipe asunsi ni a n lo tabi
- Afipe akanmole
- Ipa ti afipe kookan ko nogba ti a ba pe iro konsonanti.
Irufe idiwo to wa fun eemi ti a lo: A gbodo so irufe idiwo ti o sele si eemi ni opona ajemohun, boya
- Ona se patapata ni; tabi
- Alafo die si sile fun eemi lati koja
A le wa se apejuwe abuda iro konsonanti ni okookan bayii. Bi apeere: iro /b/:
- Orison eemi – eemi edo-foro ni a lo
- Irufe eemi – eemi amisode
- Ipo alafo tan-an-na – alafo tan-an-na wan i ipo ikun
- Ipo afase – afase gbera soke di ona si imu
- Irufe afipe – ete isale (asunsi) pade ete oke (akanmole)
- Iru idiwo – ona eemi se patapata ni sakani ete mejeeji
ATE KONSONANTI
Ate yii fi gbogbo alaye wa lori owoo konsonanti han ni soki.
Ona Isenupe | Afeji-ete-pe | Afeyin-fete-pe | Aferi-gipe | Afaja-fe-rigi-pe | Afajape | Afafasepe | Afitan-an-nape | Afafa-sefete-pe | |
Asenupe | Akunyun
Aikunyin |
b | d
t |
g
k |
gb
p |
||||
Aseesetan | Akunyun | y | w | ||||||
Asesi | Akunyun | j | |||||||
Afunnupe | Aikunyun | f | s | ṣ | h | ||||
Afegbe-enu-pe | Akunyun | l | |||||||
Aranmupe | Akunyun | m | n | ||||||
Arehon | Akunyun | r |
DIDARUKO IRO KONSONANTI
A le se apejuwe iro konsonanti bayii:
[b] Konsonanti akunyun afeji-ete-pe asenupe
[d] konsonanti akunyun aferigipe asenupe
[g] Konsonanti akunyun afafasepe asenupe
[gb] Konsonanti akunyun afafasefetepe asenupe
[f] Konsoanti aikunyun afeyinfete afunnupe
[h] Konsonanti aikunyun afitan-an-nape afunnupe
[dz] Konsonanti akunyun afajaferigipe asesi
[k] Konsonanti aikunyun afafasepe asenupe
[l] Konsonanti akunyun aferigipe afegbe-enu-pe
[m] Konsonanti akunyun afeji-ete-pe aranmu
[n] Konsonanti akunyun aferigipe aranmu
[kp] Konsonanti aikunyun afafasefetepe asenupe
[r] Konsonanti akunyun aferigipe arehon
[s] Konsonanti aikunyun aferigipe afunnupe
[ʃ] Konsonanti aikunyun afajaferigipe afunnupe
[t] Konsonanti aikunyun aferigipe asenupe
[w] Konsonanti akunyun afafasefetepe aseesetan
[j] Konsonanti akunyun afajape aseesetan.
IRO FAWELI: Faweli ni awon iro ti a pe jade nigba ti ko si idiwo Kankan fun eemi to n ti inu edo-foro bo.
Iro faweli ede Yoruba pin si orisii meji. Awon ni:
- Faweli airanmupe: a, e, ҿ, i, o, ϙ, u
- Faweli aranmupe: an, ҿn, in, ϙn, un
Lati se apejuwe abuda iro faweli ede Yoruca, a nilati ye ipo ti awon eya ara ifo meta wonyi wa wo:
- ahon
- afase, ati
- ete
Ipo ti ahon wa: A gbodo se akiyesi
- apa kan ara ahon to gbe soke julo ninu enu (boya iwaju, aarin tabi eyin ahon)
- bi apa kan to gbe soke naa se ga to ni enu. Bi apeere, bi a ba pe iro /i/:
- iwaju ahon lo gbe soke jule ni enu
- giga iwaju ahon feree de oke tente ni enu
ATE FAWELI: Ate isaje yii ni so ipo tabi irisi ahon ni enu ti a ba gbe iro faweli kookan jade.
Faweli airanmupe
See also
AKORI EKO: ATUNYEWO AWON EYA ARA IFO
AKORI EKO: ITESIWAJU AWON ORISA ILE YORUBA
AKORI EKO: ITESIWAJU ONKA YORUBA